1 OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní,
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni ninu yín bá fẹ́ mú ọrẹ ẹbọ wá fún èmi OLUWA, ninu agbo mààlúù, tabi agbo ewúrẹ́, tabi agbo aguntan rẹ̀ ni kí ó ti mú un.
3 “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.
4 Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.
5 Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
6 Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́;
7 kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i.
8 Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to àwọn igẹ̀ ẹran náà ati orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ sórí igi tí wọ́n dáná sí, lórí pẹpẹ náà.
9 Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.
10 “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú.
11 Kí ó pa á ní apá ìhà àríwá pẹpẹ níwájú OLUWA, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yíká.
12 Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀, ati ọ̀rá rẹ̀, kí alufaa to gbogbo rẹ̀ sórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ.
13 Ṣugbọn kí ó fi omi fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, kí alufaa fi gbogbo rẹ̀ rúbọ, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ náà. Ẹbọ sísun ni; ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA dùn sí.
14 “Bí ó bá jẹ́ pé ẹyẹ ni eniyan bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, kí ó mú àdàbà tabi ọmọ ẹyẹlé wá.
15 Alufaa yóo gbà á, yóo fa ọrùn rẹ̀ tu, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ, lẹ́yìn tí ó bá ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ tán;
16 kí ó fa àjẹsí rẹ̀ yọ, kí ó sì tu ìyẹ́ rẹ̀, kí ó dà á sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ náà, níbi tí wọn ń da eérú sí.
17 Kí ó fa apá rẹ̀ mejeeji ya, ṣugbọn kí ó má fà wọ́n já. Lẹ́yìn náà kí alufaa sun ún lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA.