Lefitiku 8 BM

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

3 Lẹ́yìn náà, kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”

4 Mose bá pe gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5 Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA pàṣẹ pé ẹ gbọdọ̀ ṣe nìyí.”

6 Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n.

7 Ó gbé ẹ̀wù náà wọ Aaroni, ó sì dì í ní àmùrè rẹ̀, ó gbé aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ wọ̀ ọ́ ati efodu rẹ̀, ó sì fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára dì í lámùrè.

8 Ó mú ìgbàyà, ó so ó mọ́ ọn láyà, ó sì fi Urimu ati Tumimu sí ara ìgbàyà náà.

9 Ó fi fìlà dé e lórí, ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, adé mímọ́ tíí ṣe àmì ìyàsímímọ́, sí iwájú fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún Mose.

10 Mose gbé òróró ìyàsímímọ́, ó ta á sí gbogbo ara Àgọ́ náà ati ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, ó sì yà wọ́n sí mímọ́.

11 Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́.

12 Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́.

13 Mose kó àwọn ọmọ Aaroni, ó wọ̀ wọ́n lẹ́wù, ó sì dì wọ́n ní àmùrè, ó dé wọn ní fìlà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

14 Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí.

15 Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.

16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú mààlúù náà, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tó wà lára wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ.

17 Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

18 Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

19 Lẹ́yìn náà, Mose pa á, ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yípo.

20 Wọ́n gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sun gbogbo rẹ̀ pẹlu orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ.

21 Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22 Lẹ́yìn náà, ó fa àgbò keji kalẹ̀, èyí tí í ṣe àgbò ìyàsímímọ́. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

23 Lẹ́yìn náà Mose pa á, ó tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi kan etí ọ̀tún Aaroni, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24 Wọ́n mú àwọn ọmọ Aaroni náà jáde, Mose tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi kan etí ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sórí pẹpẹ yípo.

25 Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀.

26 Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà.

27 Ó kó gbogbo rẹ̀ lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

28 Lẹ́yìn náà, Mose gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sísun bí ẹbọ ìyàsímímọ́, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLÚWA.

29 Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.

30 Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn.

31 Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.

32 Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún.

33 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà fún ọjọ́ meje títí tí ọjọ́ ètò ìyàsímímọ́ yín yóo fi pé; nítorí ọjọ́ meje gbáko ni ètò ìyàsímímọ́ yín yóo gbà.

34 Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

35 Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.”

36 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ láti ẹnu Mose.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27