1 OLUWA ní kí Mose,
2 sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
3 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí mò ń ko yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà wọn.
4 Àwọn òfin mi ni ẹ gbọdọ̀ pamọ́, àwọn ìlànà mi sì ni ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé, tí ẹ sì gbọdọ̀ máa tọ̀. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
5 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ máa tẹ̀lé ìlànà mi kí ẹ sì máa pa àwọn òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ń pa wọ́n mọ́ yóo wà láàyè. Èmi ni OLUWA.
6 “Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ tọ ìbátan rẹ̀ lọ láti bá a lòpọ̀. Èmi ni OLUWA.
7 Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ bá ìyá rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé, bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni, ìyá rẹ ni, o kò gbọdọ̀ tú ìyá rẹ síhòòhò.
8 O kò gbọdọ̀ bá aya baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé bí ẹni ń tú baba ẹni síhòòhò ni.
9 O kò gbọdọ̀ bá arabinrin rẹ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lobinrin, tabi ọmọ baba rẹ lobinrin, kì báà jẹ́ pé ilé ni wọ́n bí i sí tabi ìdálẹ̀.
10 O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ.
11 O kò gbọdọ̀ bá ọmọ tí aya baba rẹ bá bí fún baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, arabinrin rẹ ni.
12 O kò gbọdọ̀ bá arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí baba rẹ ni ó jẹ́.
13 O kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹbí ìyá rẹ ni ó jẹ́.
14 O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún ọ.
15 O kò gbọdọ̀ bá aya ọmọ rẹ lòpọ̀, nítorí pé, aya ọmọ rẹ ni.
16 O kò gbọdọ̀ bá aya arakunrin rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ohun ìtìjú ni, ìhòòhò arakunrin rẹ ni.
17 O kò gbọdọ̀ bá obinrin kan lòpọ̀ tán, kí o tún bá ọmọ rẹ̀ obinrin lòpọ̀ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ obinrin, nítorí pé, ẹbí rẹ̀ ni wọ́n jẹ́, ìwà burúkú ni èyí jẹ́.
18 O kò gbọdọ̀ fi ọmọ ìyá, tabi ọmọ baba iyawo rẹ ṣe aya níwọ̀n ìgbà tí aya rẹ tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bá wà láàyè.
19 “O kò gbọdọ̀ bá obinrin lòpọ̀, nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.
20 O kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí o sì sọ ara rẹ di aláìmọ́ pẹlu rẹ̀.
21 O kò gbọdọ̀ fa èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ kalẹ̀ fún lílò níbi ìbọ̀rìṣà Moleki, kí o sì ti ipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọrun rẹ jẹ́. Èmi ni OLUWA.
22 O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni.
23 O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni.
24 “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́.
25 Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde.
26 Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, ati àwọn òfin mi wọnyi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, kì báà jẹ́ onílé ninu yín, tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín.
27 Nítorí pé gbogbo àwọn ohun ìríra wọnyi ni àwọn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe, tí wọ́n sì fi ba ilẹ̀ náà jẹ́.
28 Kí ilẹ̀ náà má baà ti ẹ̀yin náà jáde nígbà tí ẹ bá bà á jẹ́, bí ó ti ti àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ ṣáájú yín jáde.
29 Nítorí pé, a óo yọ àwọn tí wọ́n bá ṣe àwọn ohun ìríra kúrò láàrin àwọn eniyan wọn.
30 “Nítorí náà, ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ má sì ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, tí àwọn tí wọ́n ṣáájú yín ṣe, kí ẹ má fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”