Lefitiku 19 BM

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Jẹmọ́ Ẹ̀tọ́ ati Jíjẹ́ Mímọ́

1 OLUWA sọ fún Mose

2 pé kí ó sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA Ọlọrun yín.

3 Olukuluku yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá ati baba rẹ̀, kí ó sì pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

4 “Ẹ kò gbọdọ̀ yipada kí ẹ lọ bọ oriṣa tabi kí ẹ yá ère kankan fún ara yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

5 “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

6 Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú ẹbọ náà gan-an tabi ní ọjọ́ keji rẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ohun tí ẹ fi rúbọ tán. Bí ohunkohun bá kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni ẹ gbọdọ̀ dáná sun ún.

7 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́.

8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

9 “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé.

10 O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.

11 “Ẹ kò gbọdọ̀ jalè, ẹ kò gbọdọ̀ fi ìwà ẹ̀tàn bá ara yín lò; ẹ kò sì gbọdọ̀ parọ́ fún ara yín.

12 Ẹ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí ẹ má baà ba orúkọ Ọlọrun yín jẹ́. Èmi ni OLUWA.

13 “Ẹ kò gbọdọ̀ pọ́n aládùúgbò yín lójú tabi kí ẹ jà á lólè; owó iṣẹ́ tí alágbàṣe bá ba yín ṣe kò gbọdọ̀ di ọjọ́ keji lọ́wọ́ yín.

14 Ẹ kò gbọdọ̀ gbé adití ṣépè tabi kí ẹ gbé ohun ìdìgbòlù kalẹ̀ níwájú afọ́jú, ṣugbọn ẹ níláti bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.

15 “Ẹ kò gbọdọ̀ dájọ́ èké, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka tabi ọlọ́rọ̀, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ àwọn aládùúgbò yín pẹlu òdodo.

16 Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe òfófó káàkiri láàrin àwọn eniyan yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kọ̀ láti jẹ́rìí aládùúgbò yín, bí ẹ̀rí yín bá lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Èmi ni OLUWA.

17 “Ẹ kò gbọdọ̀ di arakunrin yín sinu, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa sọ àsọyé pẹlu aládùúgbò yín, kí ẹ má baà gbẹ̀ṣẹ̀ nítorí tirẹ̀.

18 Ẹ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san, tabi kí ẹ di ọmọ eniyan yín sinu, ṣugbọn ẹ níláti fẹ́ràn ọmọnikeji yín gẹ́gẹ́ bí ara yín. Èmi ni OLUWA.

19 “Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà mi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí oríṣìí meji ninu àwọn ohun ọ̀sìn yín gun ara wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gbin oríṣìí èso meji sinu oko kan náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fi oríṣìí aṣọ meji dá ẹ̀wù kan ṣoṣo.

20 “Bí ọkunrin kan bá bá ẹrubinrin tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹlòmíràn lòpọ̀, tí wọn kò bá tíì ra ẹrubinrin náà pada, tabi kí wọ́n fún un ní òmìnira rẹ̀, kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ tìtorí pé ẹrú ni kí wọn pa wọ́n.

21 Ṣugbọn ọkunrin náà gbọdọ̀ mú àgbò kan tọ OLUWA wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún ara rẹ̀.

22 Alufaa yóo fi àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, OLUWA yóo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.

23 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

24 Ní ọdún kẹrin, ẹ ya gbogbo àwọn èso náà sọ́tọ̀ fún rírú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA.

25 Ṣugbọn ní ọdún karun-un, ẹ lè jẹ èso wọn, kí wọ́n lè máa so sí i lọpọlọpọ. Èmi ni OLUWA.

26 “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ lọ máa woṣẹ́, tabi kí ẹ gba àjẹ́. Diut 18:10

27 Ẹ kò gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ irun orí yín tabi kí ẹ gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n yín.

28 Ẹ kò gbọdọ̀ ya ara yín lábẹ nítorí òkú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fín ara yín rárá. Èmi ni OLUWA.

29 “Ẹ kò gbọdọ̀ ba ọmọbinrin yín jẹ́, nípa fífi ṣe aṣẹ́wó; kí ilẹ̀ náà má baà di ilẹ̀ àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú.

30 Ẹ gbọdọ̀ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ wọ ilé mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

31 “Ẹ kò gbọdọ̀ kó ọ̀rọ̀ yín lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláyẹ̀wò tabi àwọn abókùúsọ̀rọ̀, kí wọ́n má baà sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA.

32 “Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ogbó, kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà; kí ẹ sì máa bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.

33 “Nígbà tí àlejò kan bá wọ̀ tì yín ninu ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi.

34 Bí ẹ ti ń ṣe sí ọmọ onílé ni kí ẹ máa ṣe sí àlejò tí ó wọ̀ sọ́dọ̀ yín, ẹ fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara yín, nítorí pé ẹ̀yin pàápàá ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

35 “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣèrú nígbà tí ẹ bá ń wọn nǹkan fún eniyan, kì báà jẹ́ ohun tí a fi ọ̀pá wọ̀n, tabi ohun tí a fi òṣùnwọ̀n wọ̀n, tabi ohun tí a kà,

36 òṣùnwọ̀n yín gbọdọ̀ péye: ìwọ̀n efa tí ó péye ati ìwọ̀n hini tí ó péye ni ẹ gbọdọ̀ máa lò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.

37 Ẹ gbọdọ̀ máa pa gbogbo ìlànà mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo òfin mi. Èmi ni OLUWA.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27