Lefitiku 26 BM

Ibukun fún Ìgbọràn

1 “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

2 Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

3 “Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìlànà mi, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin mi mọ́,

4 n óo mú kí òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀, ilẹ̀ yóo mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi inú oko yóo sì máa so èso.

5 Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu.

6 “N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.

7 Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n.

8 Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n.

9 N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín.

10 Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.

11 N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín.

12 N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi.

13 Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan.

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

14 “Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tèmi, tí ẹ kò sì pa gbogbo àwọn òfin mi mọ́,

15 bí ẹ bá Pẹ̀gàn àwọn ìlànà mi, tí ọkàn yín sì kórìíra ìdájọ́ mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ kọ̀ láti pa àwọn òfin mi mọ́, tí ẹ̀ ń ba majẹmu mi jẹ́,

16 ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́.

17 N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín.

18 “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

19 Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

20 Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so.

21 “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

22 N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.

23 “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,

24 èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25 N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.

26 Nígbà tí mo bá gba oúnjẹ lẹ́nu yín, obinrin mẹ́wàá ni yóo máa jókòó nídìí ẹyọ ààrò kan ṣoṣo láti ṣe burẹdi. Wíwọ̀n ni wọn yóo máa wọn oúnjẹ le yín lọ́wọ́; ẹ óo jẹ, ṣugbọn ẹ kò ní yó.

27 “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi,

28 n óo fi ibinu kẹ̀yìn sí yín, n óo sì jẹ yín níyà fúnra mi, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

29 Ebi yóo pa yín tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo máa pa àwọn ọmọ yín jẹ.

30 N óo wó àwọn ilé ìsìn yín gbogbo tí wọ́n wà lórí òkè, n óo wó àwọn pẹpẹ turari yín lulẹ̀; n óo kó òkú yín dà sórí àwọn oriṣa yín, ọkàn mi yóo sì kórìíra yín.

31 N óo sọ àwọn ìlú yín di ahoro, àwọn ilé ìsìn yín yóo sì ṣófo, n kò ní gba ẹbọ yín mọ́.

32 N óo run ilẹ̀ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu yóo fi ya àwọn ọ̀tá yín, tí wọn yóo pada wá tẹ̀dó ninu rẹ̀.

33 N óo fọ́n yín káàkiri ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, idà ni wọn yóo máa fi pa yín ní ìpakúpa, ilẹ̀ yín ati àwọn ìlú yín yóo di ahoro.

34 Nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, ilẹ̀ ti ẹ̀yin pàápàá yóo wá ní ìsinmi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà ní ahoro, ilẹ̀ yín yóo gbádùn ìsinmi rẹ̀.

35 Nígbà tí ó bá wà ní ahoro, yóo ní irú ìsinmi tí kò ní rí ni àkókò ìsinmi yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀.

36 “Ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n bá kù, n óo da jìnnìjìnnì bo ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lásán yóo máa lé wọn sá; wọn yóo sì máa sá àsá-dojúbolẹ̀ bí ẹni pé ogun ní ń lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn.

37 Wọn yóo máa ṣubú lórí ara wọn bí ẹni tí ogun ń lé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń lé wọn. Kò sì ní sí agbára fun yín láti dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín.

38 Ẹ óo parun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóo sì gbé yín mì.

39 Ìwọ̀nba ẹ̀yin tí ẹ bá ṣẹ́kù, kíkú ni ẹ óo máa kú sára lórí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, nítorí àìdára yín ati ti àwọn baba yín.

40 “Ṣugbọn bí wọn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, nípa ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí mi, ati lílòdì tí wọ́n lòdì sí mi,

41 tí mo fi kẹ̀yìn sí wọn, tí mo fi mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; bí ọkàn wọn tí ó ti yigbì tẹ́lẹ̀ bá rọ̀, tí wọ́n bá sì ṣe àtúnṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

42 n óo ranti majẹmu tí mo bá Jakọbu, ati Isaaki, ati Abrahamu dá, n óo sì ranti ilẹ̀ náà.

43 Ṣugbọn wọn yóo jáde kúrò ninu ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sì ní ìsinmi nígbà ti ó bá wà ní ahoro, nígbà tí wọn kò bá sí níbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ gba ìjẹníyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé, wọ́n kẹ́gàn ìdájọ́ mi, wọ́n sì kórìíra ìlànà mi.

44 Sibẹsibẹ nígbà tí wọ́n bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n kò ní ṣàì náání wọn; bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kórìíra wọn débi pé kí n pa wọ́n run patapata, kí n sì yẹ majẹmu mi pẹlu wọn, nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

45 Ṣugbọn n óo tìtorí tiwọn ranti majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, àní àwọn tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, kí n lè jẹ́ Ọlọrun wọn. Èmi ni OLUWA.”

46 Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA fi lélẹ̀ láàrin òun ati àwọn ọmọ Israẹli, láti ọwọ́ Mose.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27