Ẹkisodu 40 BM

Kíkọ́ ati Yíya Àgọ́ Ìpàdé OLUWA sí Mímọ́

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ọjọ́ kinni oṣù kinni.

3 Kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí tí òfin mẹ́wàá wà ninu rẹ̀ sinu àgọ́ náà, kí o sì ta aṣọ ìbòjú dí i.

4 Lẹ́yìn náà, gbé tabili náà wọ inú rẹ̀, pẹlu àwọn nǹkan tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, kí o sì tò wọ́n sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀pá fìtílà náà wọ inú rẹ̀, kí o sì to àwọn fìtílà orí rẹ̀ sí ààyè wọn.

5 Lẹ́yìn náà, gbé pẹpẹ wúrà turari siwaju àpótí ẹ̀rí náà, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

6 Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ mímọ́ ti àgọ́ àjọ náà.

7 Gbé agbada omi náà sí ààrin, ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà, kí o sì pọn omi sinu rẹ̀.

8 Lẹ́yìn náà, ṣe àgbàlá yí i ká, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

9 “Lẹ́yìn náà, mú òróró ìyàsímímọ́, kí o ta á sí ara àgọ́ náà, ati sí ara ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, kí o yà á sí mímọ́ pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, wọn yóo sì di mímọ́.

10 Ta òróró sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun pẹlu, ati sí ara gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, kí o ya pẹpẹ náà sí mímọ́, pẹpẹ náà yóo sì di ohun mímọ́ jùlọ.

11 Ta òróró sí ara agbada náà pẹlu ati gbogbo ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́.

12 “Lẹ́yìn náà, mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

13 Kó àwọn ẹ̀wù mímọ́ náà wọ Aaroni, ta òróró sí i lórí, kí o sì yà á sí mímọ́ kí ó lè máa ṣe alufaa mi.

14 Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá pẹlu, kí o sì wọ̀ wọ́n ní ẹ̀wù.

15 Ta òróró sí wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí o ti ta á sí baba wọn lórí, kí àwọn náà lè máa ṣe alufaa mi. Òróró tí o bá ta sí wọn lórí ni yóo sọ àwọn ati gbogbo ìran wọn di alufaa títí lae.”

16 Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un patapata.

17 Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún keji ni wọ́n pa àgọ́ náà.

18 Mose pa àgọ́ mímọ́ náà, ó to àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀ lé wọn, ó fi àwọn igi ìdábùú àgọ́ náà dábùú àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn òpó rẹ̀ nàró.

19 Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

20 Ó kó àwọn tabili òkúta mejeeji sinu àpótí ẹ̀rí náà, ó ti àwọn ọ̀pá àpótí náà bọ inú àwọn òrùka rẹ̀, ó sì fi ìdérí rẹ̀ dé e lórí.

21 Ó gbé àpótí ẹ̀rí náà sinu àgọ́ náà, ó sì ta aṣọ ìbòjú rẹ̀ dí i gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

22 Ó gbé tabili náà sí inú àgọ́, ní apá ìhà àríwá àgọ́ mímọ́, níwájú aṣọ ìbòjú,

23 ó sì to àwọn burẹdi náà létòlétò sórí rẹ̀ níwájú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà náà sinu àgọ́ àjọ níwájú tabili ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà.

25 Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

26 Ó gbé pẹpẹ wúrà náà kalẹ̀ ninu àgọ́ àjọ níwájú aṣọ ìbòjú náà,

27 ó sì sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

28 Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn.

29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

30 Ó gbé agbada omi náà kalẹ̀ ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ó sì pọn omi sinu rẹ̀.

31 Omi yìí ni Mose, ati Aaroni ati àwọn ọmọ Aaroni fi ń fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn,

32 nígbà tí wọ́n bá ń wọ inú àgọ́ àjọ lọ, ati ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ súnmọ́ ìdí pẹpẹ, wọn á fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ.

33 Ó ṣe àgbàlá kan yí àgọ́ ati pẹpẹ náà ká, ó ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí gbogbo iṣẹ́ náà.

Ìkùukùu Bo Àgọ́ OLUWA

34 Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀.

35 Mose kò sì lè wọ inú rẹ̀ nítorí ìkùukùu tí ó wà lórí rẹ̀, ati pé ògo OLUWA kún inú rẹ̀.

36 Ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, nígbà tí ìkùukùu yìí bá gbéra kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli á gbéra, wọ́n á sì tẹ̀síwájú.

37 Ṣugbọn bí ìkùukùu yìí kò bá tíì gbéra, àwọn náà kò ní tíì tẹ̀síwájú títí tí yóo fi gbéra.

38 Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli.