1 “Lẹ́yìn náà, pe Aaroni arakunrin rẹ sọ́dọ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ wọnyi: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n sì jẹ́ alufaa mi.
2 Sì dá ẹ̀wù mímọ́ kan fún Aaroni, arakunrin rẹ, kí ó lè fún un ní iyì ati ọlá.
3 Pe gbogbo àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ ọnà jọ, àwọn tí mo fi ìmọ̀ ati òye iṣẹ́ ọnà dá lọ́lá, kí wọ́n rán aṣọ alufaa kan fún Aaroni láti yà á sọ́tọ̀ fún mi, gẹ́gẹ́ bí alufaa.
4 Àwọn aṣọ tí wọn yóo rán náà nìwọ̀nyí; ọ̀kan fún ìgbàyà, ati ẹ̀wù efodu, ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ kan, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè kan tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí; fìlà kan, ati àmùrè. Wọn yóo rán àwọn aṣọ mímọ́ náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.
5 Wọn yóo gba wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.
6 “Wọn yóo ṣe efodu wúrà, ati aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́; wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.
7 Kí wọ́n rán àgbékọ́ meji mọ́ etí rẹ̀ mejeeji, tí wọn yóo fi lè máa so ó pọ̀.
8 Irú aṣọ kan náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni kí wọ́n fi ṣe àmùrè rẹ̀. Iṣẹ́ ọnà kan náà ni kí wọ́n ṣe sí i lára pẹlu wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.
9 Mú òkúta onikisi meji, kí o sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn.
10 Orúkọ ẹ̀yà mẹfa sára òkúta ekinni ati orúkọ ẹ̀yà mẹfa yòókù sára ekeji, kí o to àwọn orúkọ náà bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀lé ara wọn.
11 Bí oníṣẹ́ ọnà wúrà ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì, ni kí o kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sí ara òkúta mejeeji, kí o sì fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn.
12 Lẹ́yìn náà, rán àwọn òkúta mejeeji mọ́ àwọn èjìká efodu náà, gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Èyí yóo mú kí Aaroni máa mú orúkọ wọn wá siwaju OLUWA fún ìrántí.
13 O óo ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà,
14 ati ẹ̀wọ̀n wúrà meji tí a lọ́ pọ̀ bí okùn, kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà náà.
15 “Ṣe ìgbàyà ìdájọ́, èyí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà ara efodu náà: wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni kí o fi ṣe é.
16 Bákan náà ni ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí, ìṣẹ́po meji ni yóo jẹ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìká kọ̀ọ̀kan.
17 To òkúta olówó iyebíye sí ara rẹ̀ ní ẹsẹ̀ mẹrin, kí ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ òkúta sadiu, ati òkúta topasi, ati òkúta kabọnku.
18 Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi.
19 Kí ẹsẹ̀ kẹta jẹ́ òkúta jasiniti, ati òkúta agate, ati òkúta ametisti.
20 Kí ẹsẹ̀ kẹrin jẹ́ òkúta bẹrili, ati òkúta onikisi, ati òkúta jasiperi, wúrà ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òkúta wọnyi.
21 Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.
22 Fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà.
23 Kí o da òrùka wúrà meji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.
24 Fi ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji bọ inú òrùka mejeeji yìí.
25 So etí kinni keji àwọn ẹ̀wọ̀n mejeeji mọ́ ojú ìdè mejeeji, kí o so ó mọ́ èjìká efodu náà níwájú.
26 Da òrùka wúrà meji, sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà lọ́wọ́ inú, ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.
27 Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.
28 Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ aró ni wọn yóo máa fi bọ inú àwọn òrùka ara efodu ati àwọn òrùka ara ìgbàyà, láti dè wọ́n pọ̀ kí ó lè máa wà lórí àmùrè tí ó wà lára efodu náà, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu.
29 “Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli yóo máa wà lára Aaroni, lórí ìgbàyà ìdájọ́, ní oókan àyà rẹ̀, nígbà tí ó bá wọ ibi mímọ́ lọ, fún ìrántí nígbà gbogbo níwájú OLUWA.
30 Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA.
31 “O óo fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà.
32 Yọ ọrùn sí ẹ̀wù náà, kí o sì fi aṣọ bí ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a lọ́rùn yípo, bí wọ́n ti máa ń fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá ọrùn ẹ̀wù, kí ó má baà ya.
33 Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀.
34 Agogo wúrà kan, àwòrán èso pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni kí o tò wọ́n sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà.
35 Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú.
36 “Fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí kan kí o sì kọ àkọlé sí i gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, àkọlé náà nìyí: ‘Mímọ́ fún OLUWA.’
37 Fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́, aláwọ̀ aró dè é mọ́ fìlà alufaa níwájú.
38 Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi.
39 “Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dá ẹ̀wù fún Aaroni, kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rán fìlà rẹ̀ pẹlu, lẹ́yìn náà rán àmùrè tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára fún un.
40 “Rán ẹ̀wù ati àmùrè, ati fìlà fún àwọn ọmọ Aaroni fún ògo ati ẹwà.
41 Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.
42 Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dá ṣòkòtò fún wọn; láti máa fi bo ìhòòhò wọn, láti ìbàdí títí dé itan.
43 Kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ ṣòkòtò náà, nígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa ni ibi mímọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú. Títí laelae ni òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa pa ìlànà yìí mọ́.