1 “Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.”
2 Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.
3 Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀.
4 Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ;
5 wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.”
6 Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́;
7 nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.
8 Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i.
9 Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà.
10 Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
11 Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà.
12 Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn.
13 Wọ́n ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, wọ́n fi àwọn ìkọ́ náà kọ́ àránpọ̀ aṣọ títa náà mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni àgọ́ náà ṣe di odidi kan.
14 Wọ́n tún mú aṣọ títa mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, wọ́n rán an pọ̀, wọ́n fi ṣe ìbòrí sí àgọ́ náà.
15 Gígùn aṣọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin; bákan náà ni òòró ati ìbú àwọn aṣọ mọkọọkanla.
16 Wọ́n rán marun-un pọ̀ ninu àwọn aṣọ títa náà, lẹ́yìn náà ó rán mẹfa yòókù pọ̀.
17 Wọ́n ṣe aadọta ojóbó sára èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ kinni, ati èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ keji.
18 Wọ́n sì ṣe aadọta ìkọ́ idẹ láti fi mú aṣọ àgọ́ náà papọ̀ kí ó lè di ẹyọ kan ṣoṣo.
19 Wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní pupa ati awọ ewúrẹ́ ṣe ìbòrí àgọ́ náà.
20 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi igi akasia ṣe àkànpọ̀ igi tí ó dúró lóòró fún àgọ́ náà.
21 Gígùn àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.
22 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àkànpọ̀ igi náà ní ìkọ́ meji meji láti fi mú wọn pọ̀ mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbogbo àwọn àkànpọ̀ igi àgọ́ náà.
23 Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún apá gúsù àgọ́ náà,
24 wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji.
25 Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ mímọ́ náà,
26 pẹlu ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka; ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.
27 Wọ́n ṣe àkànpọ̀ igi mẹfa fún ẹ̀yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.
28 Wọ́n sì ṣe àkànpọ̀ igi meji fún igun àgọ́ náà tí ó wà ní apá ẹ̀yìn.
29 Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà.
30 Àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní igun kinni-keji jẹ́ mẹjọ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrindinlogun, ìtẹ́lẹ̀ meji meji wà lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.
31 Wọ́n fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú mẹẹdogun, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ gúsù,
32 marun-un fún àwọn ti ẹ̀gbẹ́ àríwá, marun-un fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn, lápá ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà.
33 Wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú kan la àwọn àkànpọ̀ igi náà láàrin, ọ̀pá náà kan igun kinni-keji àgọ́ náà.
34 Wọ́n yọ́ wúrà bo gbogbo àkànpọ̀ igi náà, wọ́n fi wúrà ṣe ìkọ́ fún àwọn àkànpọ̀ igi náà, wọ́n sì yọ́ wúrà bo àwọn ọ̀pá ìdábùú náà pẹlu.
35 Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára.
36 Wọ́n fi igi akasia ṣe òpó mẹrin, wọ́n sì yọ́ wúrà bò ó. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, wọ́n sì fi fadaka ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹrin fún àwọn òpó náà.
37 Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà sí i lára.
38 Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun.