Ẹkisodu 6 BM

1 Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.”

Ọlọrun Pe Mose

2 Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA.

3 Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an.

4 Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò.

5 Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi.

6 Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá.

7 N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín.

8 N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ”

9 Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì.

10 OLUWA bá sọ fún Mose pé,

11 “Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.”

12 Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.”

13 Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

Àkọsílẹ̀ Ìran Mose ati Ti Aaroni

14 Èyí ni àkọsílẹ̀ àwọn olórí olórí ninu ìdílé wọn: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu bí ọmọkunrin mẹrin: Hanoku, Palu, Hesironi ati Karimi; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Reubẹni.

15 Simeoni bí ọmọkunrin mẹfa: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani kan bí fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Simeoni.

16 Lefi bí ọmọ mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Lefi gbé láyé.

17 Geriṣoni bí ọmọ meji: Libini ati Ṣimei, wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn.

18 Kohati bí ọmọ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Ọdún mẹtalelaadoje (133) ni Kohati gbé láyé.

19 Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí arọmọdọmọ wọn.

20 Amramu fẹ́ Jokebedi, arabinrin baba rẹ̀. Jokebedi sì bí Aaroni ati Mose fún un. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Amramu gbé láyé.

21 Iṣari bí ọmọkunrin mẹta: Kora, Nefegi ati Sikiri.

22 Usieli bí ọmọkunrin mẹta: Miṣaeli, Elisafani ati Sitiri.

23 Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari.

24 Kora bí ọmọkunrin mẹta: Asiri, Elikana ati Abiasafu; àwọn ni ìdílé Kora.

25 Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Putieli; ó sì bí Finehasi fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi.

26 Aaroni ati Mose ni OLUWA pè, tí ó sì wí fún pé kí wọ́n kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

27 Àwọn ni wọ́n sọ fún ọba Ijipti pé kí ó dá àwọn eniyan Israẹli sílẹ̀.

Àṣẹ Tí OLUWA Pa fún Mose ati Aaroni

28 Ní ọjọ́ tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Ijipti,

29 OLUWA sọ fún un pé, “Èmi ni OLUWA, sọ gbogbo ohun tí mo rán ọ fún Farao, ọba Ijipti.”

30 Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “OLUWA, akólòlò ni mí; báwo ni ọba Farao yóo ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi?”