Ẹkisodu 21 BM

Ojúṣe Olówó Ẹrú sí Ẹrú

1 “Àwọn òfin tí o gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí:

2 Bí ẹnikẹ́ni bá ra Heberu kan lẹ́rú, ọdún mẹfa ni ẹrú náà óo fi sìn ín, ní ọdún keje, ó níláti dá a sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀.

3 Bí ó bá jẹ́ pé òun nìkan ni ó rà, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹrú náà bá mú aya rẹ̀ lọ́wọ́ wá, bí ó bá ti ń dá a sílẹ̀, ó gbọdọ̀ dá aya rẹ̀ sílẹ̀ pẹlu.

4 Bí olówó rẹ̀ bá fẹ́ aya fún un, tí aya náà sì bímọ fún un, lọkunrin ati lobinrin, olówó rẹ̀ ni ó ni aya ati àwọn ọmọ patapata, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀.

5 Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀,

6 olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé.

7 “Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin.

8 Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un.

9 Bí ó bá fẹ́ ẹ sọ́nà fún ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ó gbọdọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ gan-an.

10 Bí ó bá fẹ́ aya mìíràn fún ara rẹ̀, kò gbọdọ̀ dín oúnjẹ ẹrubinrin yìí kù, tabi aṣọ rẹ̀ tabi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya.

11 Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun.

Òfin nípa Ìwà Ipá

12 “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà.

13 Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín.

14 Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á.

15 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà.

16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.

17 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á.

18 “Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa,

19 bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn.

20 “Bí ẹnìkan bá lu ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ ní kùmọ̀, tí ẹrú náà bá kú mọ́ ọn lọ́wọ́, olúwarẹ̀ yóo jìyà.

21 Ṣugbọn bí ẹrú náà bá gbé odidi ọjọ́ kan tabi meji kí ó tó kú, kí ẹnikẹ́ni má jẹ olówó ẹrú náà níyà, nítorí òun ni ó ni owó tí ó fi rà á.

22 “Bí àwọn eniyan bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe aboyún léṣe, tóbẹ́ẹ̀ tí oyún rẹ̀ bàjẹ́ mọ́ ọn lára, ṣugbọn tí òun gan-an kò kú, ẹni tí ó ṣe aboyún náà léṣe níláti san iyekíye tí ọkọ rẹ̀ bá sọ pé òun yóo gbà bí owó ìtanràn, tí onídàájọ́ bá ti fi ọwọ́ sí i.

23 Ṣugbọn bí aboyún náà bá kú tabi bí ó bá farapa, kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣe é léṣe náà.

24 Bí ẹnìkan bá fọ́ eniyan lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà; bí ẹnìkan bá ká eniyan léyín, kí wọ́n ká eyín tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lọ́wọ́, kí wọ́n gé ọwọ́ tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lẹ́sẹ̀, kí wọ́n gé ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà.

25 Bí ẹnìkan bá fi iná jó eniyan, kí wọ́n fi iná jó òun náà, bí ẹnìkan bá ṣá eniyan lọ́gbẹ́, kí wọ́n ṣá òun náà lọ́gbẹ́, bí ẹnìkan bá na eniyan lẹ́gba, kí wọ́n na òun náà lẹ́gba.

26 “Bí ẹnìkan bá gbá ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ lójú, tí ojú náà sì fọ́, olúwarẹ̀ yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti fọ́ ọ lójú.

27 Bí ó bá yọ eyín ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀, yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé ó ti yọ ọ́ léyín.

Ojúṣe Ẹni Tí Ó ní Ohun Ọ̀sìn

28 “Bí mààlúù bá kan eniyan pa, kí wọ́n sọ mààlúù náà ní òkúta pa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ ẹni tí ó ni mààlúù náà níyà.

29 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ mààlúù náà ti kan eniyan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó ni ín, tí kò sì so ó mọ́lẹ̀, bí ó bá pa eniyan, kí wọn sọ mààlúù náà ní òkúta pa, kí wọn sì pa ẹni tí ó ni ín pẹlu.

30 Ṣugbọn bí wọ́n bá gbà pé kí ẹni tí ó ni ín san owó ìtanràn, ó níláti san iyekíye tí wọ́n bá sọ pé kí ó san, kí ó baà lè ra ẹ̀mí ara rẹ̀ pada.

31 Bí irú mààlúù tí ó ti kan eniyan pa tẹ́lẹ̀ rí yìí bá tún kan ọmọ ẹnìkan pa, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, irú ẹ̀tọ́ kan náà tí a sọ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ṣe fún ẹni tí ó ni mààlúù náà.

32 Bí mààlúù náà bá kan ẹrú ẹnìkan pa, kì báà ṣe ẹrukunrin tabi ẹrubinrin, ẹni tí ó ni mààlúù náà níláti san ọgbọ̀n ṣekeli fadaka fún ẹni tí ó ni ẹrú tí mààlúù pa, kí wọ́n sì sọ mààlúù náà ní òkúta pa.

33 “Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú,

34 ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò.

35 Bí mààlúù ẹnìkan bá pa ti ẹlòmíràn, àwọn mejeeji yóo ta mààlúù tí ó jẹ́ ààyè, wọn yóo pín owó rẹ̀, wọn yóo sì pín òkú mààlúù náà pẹlu.

36 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀.