1 Mose dáhùn pé, “Wọn kò ní gbà mí gbọ́, wọn kò tilẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọn yóo wí pé, OLUWA kò farahàn mí.”
2 OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”
3 OLUWA ní, “Sọ ọ́ sílẹ̀.” Mose bá sọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò, Mose bá sá sẹ́yìn.
4 Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀.
5 OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.”
6 OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
7 Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.
8 Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́.
9 Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.”
10 Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.”
11 OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni.
12 Nítorí náà, lọ, n óo sì wà pẹlu rẹ, n óo sì máa kọ́ ọ ní ohun tí o óo sọ.”
13 Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.”
14 Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi.
15 O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe.
16 Òun ni yóo máa bá ọ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀, yóo jẹ́ ẹnu fún ọ, o óo sì dàbí Ọlọrun fún un.
17 Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.”
18 Mose pada lọ sí ọ̀dọ̀ Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan mi ní Ijipti, kí n lọ wò ó bóyá wọ́n wà láàyè.” Jẹtiro dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ ní alaafia.”
19 OLUWA sọ fún Mose ní Midiani pé, “Pada lọ sí Ijipti, nítorí pé gbogbo àwọn tí wọn ń lépa ẹ̀mí rẹ ti kú tán.”
20 Mose bá gbé iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tòun ti ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ rẹ̀.
21 OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá pada dé Ijipti, o gbọdọ̀ ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí mo fún ọ lágbára láti ṣe níwájú Farao, ṣugbọn n ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì ní jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ.
22 O óo wí fún un pé, Èmi, OLUWA wí pé, ‘Israẹli ni àkọ́bí mi ọkunrin.
23 Nítorí náà, jẹ́ kí ọmọ mi lọ, kí ó lè sìn mí. Bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí ó lọ, pípa ni n óo pa àkọ́bí rẹ ọkunrin.’ ”
24 Nígbà tí wọ́n dé ilé èrò kan ní ojú ọ̀nà Ijipti, OLUWA pàdé Mose, ó sì fẹ́ pa á.
25 Sipora bá mú akọ òkúta pẹlẹbẹ tí ó mú, ó fi kọ ilà abẹ́ fún ọmọ rẹ̀, ó sì fi awọ tí ó gé kúrò kan ẹsẹ̀ Mose, ó wí fún Mose pé, “Ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ọ́.”
26 OLUWA bá fi Mose sílẹ̀, kò pa á mọ́. Nítorí àṣà ilà abẹ́ kíkọ náà ni Sipora ṣe wí pé, ọkọ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba kí á ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni Mose.
27 OLUWA wí fún Aaroni pé, “Jáde lọ sinu aṣálẹ̀, kí o lọ pàdé Mose.” Ó jáde lọ, ó pàdé rẹ̀ ní òkè Ọlọrun, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.
28 Mose sọ gbogbo iṣẹ́ tí OLUWA rán an fún un, ati gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ó ṣe.
29 Mose ati Aaroni bá lọ sí Ijipti, wọ́n kó gbogbo àgbààgbà àwọn eniyan Israẹli jọ.
30 Aaroni sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu náà lójú gbogbo àwọn àgbààgbà náà.
31 Àwọn eniyan náà gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́; nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA wá bẹ àwọn eniyan Israẹli wò, ati pé ó ti rí ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sin OLUWA.