Ẹkisodu 30 BM

Pẹpẹ fún Sísun Turari

1 “Fi igi akasia tẹ́ pẹpẹ kan, tí wọn yóo máa sun turari lórí rẹ̀.

2 Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, fífẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ kan. Ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà, yóo sì ga ní igbọnwọ meji, àṣepọ̀ mọ́ ìwo rẹ̀ ni kí o ṣe é.

3 Fi ojúlówó wúrà bo òkè, ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, ati ìwo rẹ̀ pẹlu. Fi wúrà ṣe ìgbátí yí gbogbo etí rẹ̀ po.

4 Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà.

5 Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

6 Gbé e sílẹ̀ lóde aṣọ títa tí ó wà lẹ́bàá àpótí ẹ̀rí, lọ́gangan iwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lókè àpótí ẹ̀rí náà, níbi tí n óo ti máa ba yín pàdé.

7 Kí Aaroni máa sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀, ní àràárọ̀, nígbà tí ó bá ń tọ́jú àwọn fìtílà.

8 Nígbà tí ó bá ń gbé àwọn fìtílà náà sí ààyè wọn ní àṣáálẹ́, yóo máa sun turari náà pẹlu, títí lae ni yóo máa sun turari náà níwájú OLUWA ní ìrandíran yín.

9 Ẹ kò gbọdọ̀ sun turari tí ó jẹ́ aláìmọ́ lórí pẹpẹ náà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sun ẹbọ sísun lórí rẹ̀; tabi ẹbọ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù lórí rẹ̀.

10 Aaroni yóo máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo máa fi ṣe ètùtù náà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìrandíran yín. Pẹpẹ náà yóo jẹ́ ohun èlò tí ó mọ́ jùlọ fún OLUWA.”

Owó Orí fún Àgọ́ Wíwà OLUWA

11 OLUWA sọ fún Mose pé,

12 “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.

13 Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.

14 Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.

15 Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín.

16 Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.”

Agbada Idẹ

17 OLUWA tún wí fún Mose pé,

18 “Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀.

19 Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn.

20 Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú.

21 Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.”

Òróró Ìyàsímímọ́

22 Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé,

23 “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún,

24 ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan.

25 Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA.

26 Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí,

27 ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari,

28 ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

29 Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́.

30 Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi.

31 Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín,

32 ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ”

Turari náà

34 OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

35 Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́.

36 Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín.

37 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.

38 Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.”