Ẹkisodu 25 BM

Ọrẹ fún Àgọ́ Mímọ́

1 OLUWA rán Mose ó ní,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n gba ọrẹ jọ fún mi, ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ọkàn rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ àtinúwá ni kí wọ́n ti gba ọrẹ náà.

3 Àwọn nǹkan ọrẹ tí wọn yóo gbà lọ́wọ́ wọn ni: wúrà, fadaka, idẹ;

4 aṣọ aláró, aṣọ elése àlùkò, aṣọ pupa, aṣọ funfun, ati irun ewúrẹ́;

5 awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia;

6 òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari,

7 òkúta onikisi ati àwọn òkúta tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọnà sára efodu tí àwọn alufaa ń wọ̀, ati ohun tí wọn ń dà bo àyà;

8 kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn.

9 Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.

Àpótí Ẹ̀rí

10 “Kí wọ́n fi igi akasia kan àpótí kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó fẹ̀ ní igbọnwọ kan ààbọ̀, kí ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀.

11 Fi ojúlówó wúrà bò ó ninu ati lóde, kí o sì fi wúrà gbá a létí yípo.

12 Fi wúrà ṣe òrùka mẹrin, kí o jó wọn mọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹẹrin; meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

13 Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.

14 Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji àpótí náà láti máa fi gbé e.

15 Kí àwọn ọ̀pá yìí máa wà ninu àwọn òrùka tí ó wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí yìí nígbà gbogbo, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fà wọ́n yọ.

16 Kí o fi àkọsílẹ̀ majẹmu ẹ̀rí tí n óo gbé lé ọ lọ́wọ́ sinu àpótí náà.

17 “Lẹ́yìn náà, fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

18 Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà.

19 Àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn Kerubu náà, kí ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀, kí ekeji sì wà ní òkè rẹ̀.

20 Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà.

21 Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀.

22 Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.

Tabili fún Àkàrà Ìrúbọ sí Ọlọrun

23 “Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

24 Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo.

25 Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo.

26 Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

27 Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

28 Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.

29 Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù.

30 Gbé tabili náà kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, kí burẹdi ìfihàn sì máa wà ní orí rẹ̀ nígbà gbogbo.

Ọ̀pá Fìtílà

31 “Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan.

32 Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji.

33 Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi.

34 Kí òdòdó aláràbarà mẹrin wà lórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, kí àwọn òdòdó náà dàbí alimọndi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ so,

35 kí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kéékèèké kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó ya lára ọ̀pá fìtílà náà.

36 Àṣepọ̀ ni kí wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà, ati àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ati àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kékeré abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀. Ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n sì fi ṣe gbogbo rẹ̀.

37 Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju.

38 Ojúlówó wúrà ni kí o fi ṣe ẹnu rẹ̀ ati àwo pẹrẹsẹ rẹ̀,

39 talẹnti wúrà kan ni kí o fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà ati gbogbo ohun èlò rẹ̀.

40 Rí i dájú pé o ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè.