Ẹkisodu 39 BM

Dídá Ẹ̀wù Àwọn Alufaa

1 Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, rán ẹ̀wù aláràbarà tí àwọn alufaa yóo máa wọ̀ ninu ibi mímọ́ náà fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

2 Ó fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ rán efodu.

3 Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.

4 Wọ́n ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ meji fún èjìká efodu náà, wọ́n rán wọn mọ́ ẹ̀gbẹ́ kinni keji rẹ̀ láti máa fi so wọ́n mọ́ ara wọn.

5 Wọ́n fi irú aṣọ kan náà ṣe àmùrè dáradára kan. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é mọ́ efodu yìí láti máa fi so ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

6 Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì.

7 Ó tò wọ́n sí ara èjìká efodu náà gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Dídá Aṣọ Ìgbàyà

8 Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.

9 Bákan náà ni òòró ati ìbú aṣọ ìgbàyà náà, ìṣẹ́po aṣọ meji ni wọ́n sì rán pọ̀. Ìká kan ni òòró rẹ̀, ìká kan náà sì ni ìbú rẹ̀.

10 Wọ́n to òkúta olówó iyebíye sí i lára ní ẹsẹ̀ mẹrin, wọ́n to òkúta sadiu ati topasi ati kabọnku sí ẹsẹ̀ kinni,

11 wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji,

12 wọ́n to jasiniti, agate ati ametisti sí ẹsẹ̀ kẹta;

13 wọ́n to bẹrili ati onikisi ati Jasperi sí ẹsẹ̀ kẹrin, wọ́n sì fi ìtẹ́lẹ̀ wúrà jó wọn mọ́ ìgbàyà náà.

14 Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.

15 Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà.

16 Wọ́n ṣe ojú ìdè wúrà meji, ati òrùka wúrà meji, wọ́n fi òrùka wúrà mejeeji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.

17 Wọ́n ti àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji náà bọ àwọn òrùka mejeeji tí wọ́n wà ní etí kinni keji ìgbàyà náà.

18 Wọ́n mú etí kinni keji ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji, wọ́n so wọ́n mọ́ ojú ìdè wúrà ara ìgbàyà náà, wọ́n sì so wọ́n mọ́ èjìká efodu náà.

19 Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

20 Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

21 Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Dídá Aṣọ fún Àwọn Àlùfáà

22 Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà,

23 wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya.

24 Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀.

25 Wọ́n sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké la àwọn àwòrán èso Pomegiranate náà láàrin.

26 Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

27 Wọ́n fi aṣọ funfun dáradára dá ẹ̀wù meji fún Aaroni ati fún àwọn ọmọ rẹ̀,

28 wọ́n fi ṣe adé, ati fìlà ati ṣòkòtò.

29 Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

30 Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí adé mímọ́ náà, wọ́n sì kọ àkọlé kan sí ara rẹ̀ bí wọ́n ti ń kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, pé, “Mímọ́ fún OLUWA.”

31 Wọ́n so aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan mọ́ ọn, láti máa fi so ó mọ́ etí adé náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Wọ́n Parí Iṣẹ́ Àgọ́ Àjọ

32 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà ṣe parí, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

33 Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn;

34 ìbòrí tí wọ́n fi awọ ewúrẹ́ ati awọ àgbò ṣe tí wọ́n kùn láwọ̀ pupa, ati aṣọ ìbòjú inú àgọ́ náà.

35 Bẹ́ẹ̀ náà ni àpótí ẹ̀rí pẹlu àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́ àánú náà;

36 ati tabili náà, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ ati burẹdi ìfihàn.

37 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe, ati àwọn fìtílà orí rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati òróró ìtànná rẹ̀.

38 Bẹ́ẹ̀ sì ni pẹpẹ wúrà náà, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati aṣọ títa fún ìlẹ̀kùn àgọ́ mímọ́ náà;

39 ati pẹpẹ idẹ ati ààrò idẹ rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada idẹ ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

40 Bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ títa ti àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, ati aṣọ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, okùn rẹ̀ ati àwọn èèkàn rẹ̀, ati gbogbo ohun èlò fún ìsìn ninu àgọ́ mímọ́ náà, ati fún àgọ́ àjọ náà.

41 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀wù tí a ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà sí fún iṣẹ́ ìsìn àwọn alufaa ninu ibi mímọ́, ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa ati ẹ̀wù fún àwọn ọmọ rẹ̀ náà, tí wọn yóo fi máa ṣe iṣẹ́ wọn bí alufaa.

42 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, ni àwọn eniyan Israẹli ṣe gbogbo iṣẹ́ náà.

43 Mose wo gbogbo iṣẹ́ náà, ó rí i pé wọ́n ṣe é gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ, Mose sì súre fún wọn.