Ẹkisodu 9 BM

1 Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun.

2 Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ,

3 àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀.

4 Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli.

5 OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.”

6 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli.

7 Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ.

8 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao,

9 yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

10 Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko.

11 Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti.

12 Ṣugbọn OLUWA mú kí ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose.

13 OLUWA tún sọ fún Mose pé kí ó dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ó lọ siwaju Farao, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sin òun.

14 Nítorí pé lọ́tẹ̀ yìí, òun óo da gbogbo àjàkálẹ̀ àrùn òun bo Farao gan-an, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun OLUWA ní gbogbo ayé.

15 Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé,

16 ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.

17 Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ.

18 OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí.

19 Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.”

20 Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu.

21 Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá.

22 OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.”

23 Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti.

24 Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè.

25 Gbogbo ohun tí ó wà ninu oko ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ni yìnyín náà dà lulẹ̀, ati eniyan ati ẹranko; o sì wó gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn oko ati gbogbo igi lulẹ̀.

26 Àfi ilẹ̀ Goṣeni, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé nìkan ni yìnyín yìí kò dé.

27 Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀ nisinsinyii; OLUWA jàre, èmi ati àwọn eniyan mi ni a jẹ̀bi.

28 Ẹ bẹ OLUWA fún mi nítorí pé yìnyín ati ààrá yìí tó gẹ́ẹ́, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n kò ní da yín dúró mọ́.”

29 Mose bá dá Farao lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ninu ìlú n óo gbadura sí OLUWA, ààrá kò ní sán mọ́, bẹ́ẹ̀ ni yìnyín kò ní bọ́ mọ́, kí o lè mọ̀ pé, ti OLUWA ni ilẹ̀.

30 Ṣugbọn mo mọ̀ pé ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ kò bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun.”

31 Gbogbo ọ̀gbọ̀ ati ọkà Baali tí ó wà lóko ni ó ti bàjẹ́ patapata, nítorí pé ọkà baali ati ọ̀gbọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí so ni.

32 Ṣugbọn ọkà alikama ati ọkà ria kò bàjẹ́, nítorí pé wọn kò tètè hù.

33 Mose bá kúrò lọ́dọ̀ Farao, ó jáde kúrò ní ìlú; ó gbadura sí OLUWA, ààrá tí ń sán ati yìnyín tí ń bọ́ sì dáwọ́ dúró, òjò náà sì dá lórí ilẹ̀.

34 Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.

35 Ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Mose.