Ẹkisodu 34 BM

Àwọn Wàláà Òkúta Keji

1 Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn.

2 Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà.

3 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.”

4 Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́.

5 OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀.

6 OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́.

7 Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.”

8 Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA.

9 Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.”

Ọlọrun tún Majẹmu Ṣe

10 OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ.

11 “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ.

12 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín.

13 Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀.

14 “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí.

15 Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn.

16 Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn.

17 “Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín.

18 “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti.

19 “Tèmi ni gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ àkọ́bí, gbogbo àkọ́bí ẹran: kì báà jẹ́ ti mààlúù, tabi ti aguntan.

20 Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada. “Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí.

21 “Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi.

22 “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ ìkórè àkọ́so alikama ọkà yín, ati àjọ̀dún ìkójọ nígbà tí ẹ bá ń kórè nǹkan oko sinu abà ní òpin ọdún.

23 “Ẹẹmẹta lọdọọdun, ni gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, kí wọ́n wá sìn mí.

24 Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun.

25 “Ẹ kò gbọdọ̀ fi ẹran rúbọ sí mi pẹlu ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni ohunkohun tí ẹ bá sì fi rú ẹbọ àjọ̀dún ìrékọjá kò gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji.

26 “Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín.“Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.”

27 OLUWA wí fún Mose pé, “Kọ ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀, nítorí pé òun ni majẹmu mi dúró lé lórí pẹlu ìwọ ati Israẹli.”

28 Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà.

Mose Sọ̀kalẹ̀ láti Orí Òkè Sinai

29 Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ pada ti orí òkè Sinai dé, pẹlu wàláà ẹ̀rí meji lọ́wọ́ rẹ̀, Mose kò mọ̀ pé ojú òun ń dán, ó sì ń kọ mànàmànà, nítorí pé ó bá Ọlọrun sọ̀rọ̀.

30 Nígbà tí Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, wọ́n ṣe akiyesi pé ojú rẹ̀ ń kọ mànàmànà, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn.

31 Ṣugbọn Mose pè wọ́n, Aaroni ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.

32 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun bá a sọ lórí òkè Sinai lófin fún wọn.

33 Lẹ́yìn tí Mose bá wọn sọ̀rọ̀ tán ó fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀.

34 Ṣugbọn nígbà tí Mose bá wọlé lọ, láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, a máa mú aṣọ ìbòjú náà kúrò ní ojú títí yóo fi jáde, nígbà tí ó bá sì jáde, yóo sọ ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

35 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe akiyesi ojú Mose, pé ó ń kọ mànàmànà; Mose a sì máa fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí yóo fi di ìgbà tí yóo tún wọ ilé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀.