Ẹkisodu 26 BM

Àgọ́ Wíwà OLUWA

1 “Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà.

2 Kí gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ títa náà gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.

3 Rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán marun-un yòókù pọ̀.

4 Fi aṣọ aláwọ̀ aró ṣe ojóbó sí etí ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní òde ninu aṣọ àránpọ̀ kọ̀ọ̀kan.

5 Aadọta ojóbó ni kí o ṣe sí àránpọ̀ aṣọ kinni, lẹ́yìn náà ṣe aadọta ojóbó sí àránpọ̀ aṣọ keji, kí àwọn ojóbó náà lè kọ ojú sí ara wọn.

6 Lẹ́yìn náà, ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, kí o fi kọ́ àwọn ojóbó àránpọ̀ aṣọ mejeeji, kí àgọ́ náà lè dúró ní odidi kan ṣoṣo.

7 “Fi awẹ́ aṣọ mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ṣe ìbòrí kan fún àgọ́ náà.

8 Kí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣọ náà jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ mọkọọkanla gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.

9 Rán marun-un ninu àwọn aṣọ náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán mẹfa yòókù pọ̀, kí o ṣẹ́ aṣọ kẹfa po bo iwájú àgọ́ náà.

10 Ṣe aadọta ojóbó sí awẹ́ tí ó parí àránpọ̀ aṣọ kinni, kí o sì ṣe aadọta ojóbó sí etí awẹ́ tí ó parí aṣọ àránpọ̀ keji.

11 Fi idẹ ṣe aadọta ìkọ́, kí o sì fi wọ́n kọ́ àwọn ojóbó náà, láti mú àwọn àránpọ̀ aṣọ mejeeji náà papọ̀ kí wọ́n lè jẹ́ ìbòrí kan.

12 Jẹ́ kí ìdajì awẹ́ tí ó kù ṣẹ́ bo ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13 Jẹ́ kí igbọnwọ kọ̀ọ̀kan tí ó kù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àránpọ̀ aṣọ náà ṣẹ́ bo ẹ̀gbẹ́ kinni keji àgọ́ náà.

14 “Lẹ́yìn náà, fi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, ati awọ ewúrẹ́ tí a ṣe dáradára, ṣe ìbòrí keji fún àgọ́ náà.

15 “Igi akasia ni kí o fi ṣe àwọn òpó àgọ́ náà,

16 kí àwọn igi tí yóo dúró ní òòró gùn ní igbọnwọ mẹ́wàá, kí àwọn tí o óo fi dábùú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ààbọ̀.

17 Kí igi kọ̀ọ̀kan ní àtẹ̀bọ̀ meji, tí wọ́n tẹ̀ bọ inú ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo àwọn igi tí wọ́n wà ninu àgọ́ náà.

18 Ogún àkànpọ̀ igi ni kí o ṣe sí ìhà gúsù àgọ́ náà.

19 Ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka ni kí o ṣe sí àwọn ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan, kí ìtẹ́lẹ̀ meji wà fún àtẹ̀bọ̀ igi meji ninu olukuluku àkànpọ̀ igi náà.

20 Ṣe ogún àkànpọ̀ igi sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ náà,

21 ati ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka, meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

22 Àkànpọ̀ igi mẹfa ni kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

23 Kí o sì ṣe àkànpọ̀ igi meji meji fún igun mejeeji ẹ̀yìn àgọ́ náà.

24 Jẹ́ kí àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun àgọ́ wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn kí o so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi ìtẹ̀bọ̀ àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun mejeeji.

25 Gbogbo àkànpọ̀ igi yóo jẹ́ mẹjọ, ìtẹ́lẹ̀ fadaka wọn yóo sì jẹ́ mẹrindinlogun, meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

26 “Fi igi akasia ṣe igi ìdábùú mẹẹdogun; marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni àgọ́ náà,

27 marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ keji, marun-un yòókù fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀yìn ní apá ìwọ̀ oòrùn.

28 Kí igi ìdábùú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àkànpọ̀ igi náà gùn láti ẹ̀gbẹ́ kinni dé ẹ̀gbẹ́ keji àgọ́ náà.

29 Yọ́ wúrà bo àwọn àkànpọ̀ igi náà, kí wọ́n sì ní àwọn òrùka wúrà kí wọ́n lè máa ti àwọn igi ìdábùú náà bọ̀ ọ́, yọ́ wúrà bo àwọn igi ìdábùú náà pẹlu.

30 Bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, ni kí o ṣe kọ́ àgọ́ náà.

31 “Ṣe aṣọ títa kan, tí ó jẹ́ aláwọ̀ aró, ati elése àlùkò, ati pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n ya àwòrán Kerubu sí i lára.

32 Gbé e kọ́ sórí òpó igi akasia mẹrin, tí ó ní ìkọ́ wúrà. Wúrà ni kí o yọ́ bo gbogbo òpó náà, kí wọ́n sì wà lórí ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrin.

33 Lára àwọn àtẹ̀bọ̀ ni kí o fi àwọn aṣọ títa náà kọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ibi tí aṣọ títa náà wà, aṣọ títa yìí ni yóo ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi mímọ́ jùlọ.

34 Fi ìtẹ́ àánú sórí àpótí ẹ̀rí ninu ibi mímọ́ jùlọ.

35 Kí o gbé tabili kalẹ̀ ní ọwọ́ òde aṣọ títa náà, kí ọ̀pá fìtílà wà ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà, ní òdìkejì tabili náà, kí o sì gbé tabili náà kalẹ̀ ní apá àríwá.

36 “Fi aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí létí ṣe aṣọ títa kan fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

37 Ṣe òpó igi akasia marun-un fún aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà; wúrà ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, kí o sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ idẹ marun-un fún wọn.