Ẹkisodu 38 BM

Ṣíṣe Pẹpẹ fún Ẹbọ Sísun

1 Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ pẹpẹ náà rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta.

2 Ó ṣe ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin pẹpẹ náà, àṣepọ̀ mọ́ pẹpẹ ni ó ṣe àwọn ìwo náà, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

3 Ó fi idẹ ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ náà: àwọn bíi ìkòkò, ọ̀kọ̀, agbada, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń mú ẹran ati àwo ìfọnná; idẹ ni ó fi ṣe gbogbo wọn.

4 Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀.

5 Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

6 Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

7 Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu.

Ṣíṣe Agbada Idẹ

8 Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

Àgbàlá Àgọ́ Wíwà OLUWA

9 Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ.

10 Ogún ni àwọn òpó aṣọ títa, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn náà sì jẹ́ ogún. Idẹ ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni ó fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

11 Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

12 Gígùn aṣọ títa fún apá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ aadọta igbọnwọ, òpó rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá, àwọn àtẹ̀bọ̀ rẹ̀ náà jẹ́ mẹ́wàá; fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

13 Aṣọ títa ti iwájú àgọ́ náà, ní apá ìlà oòrùn gùn ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ.

14 Aṣọ títa fún apá kan ẹnu ọ̀nà jẹ́ igbọnwọ mẹẹdogun, ó ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta.

15 Bákan náà ni aṣọ títa ẹ̀gbẹ́ kinni keji ẹnu ọ̀nà náà rí, wọ́n gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹẹdogun mẹẹdogun, wọ́n ní òpó mẹta mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta mẹta.

16 Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ títa tí ó wà ninu àgbàlá náà.

17 Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

18 Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà.

19 Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà.

20 Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn èèkàn àgọ́ náà, ati ti gbogbo àgbàlá rẹ̀.

Oríṣìíríṣìí Irin tí Wọ́n Lò fún Àgọ́ Ẹ̀rí Wíwà OLUWA

21 Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa.

22 Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún Mose.

23 Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà.

24 Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

25 Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.

26 Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).

27 Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

28 Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

29 Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli.

30 Idẹ yìí ni ó lò láti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn àgọ́ àjọ, ati pẹpẹ onídẹ, ati àwọn idẹ inú rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò ibi pẹpẹ náà.

31 Lára rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó àgọ́ náà yípo ati àwọn èèkàn àgọ́ ati àwọn èèkàn àgbàlá inú rẹ̀.