1 Ní àkókò náà, ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Lefi fẹ́ obinrin kan tí òun náà jẹ́ ẹ̀yà Lefi.
2 Obinrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Nígbà tí ó rí i pé ọmọ náà jẹ́ arẹwà, ó gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta.
3 Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò.
4 Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.
5 Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà.
6 Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.”
7 Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?”
8 Ọmọbinrin Farao dá a lóhùn pé, “Lọ pè é wá.” Ọmọbinrin náà bá yára lọ pe ìyá ọmọ náà.
9 Ọmọbinrin Farao sọ fún ìyá ọmọ náà pé, “Gbé ọmọ yìí lọ, kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, n óo sì san owó àgbàtọ́ rẹ̀ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni obinrin náà ṣe gba ọmọ, ó sì ń tọ́jú rẹ̀.
10 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó gbé e pada fún ọmọbinrin Farao, ó sì fi ṣe ọmọ, ó sọ ọ́ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí pé láti inú omi ni mo ti fà á jáde.”
11 Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
12 Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn.
13 Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?”
14 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.”
15 Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose.Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan.
16 Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu.
17 Nígbà tí àwọn olùṣọ́-aguntan dé, wọ́n lé àwọn ọmọbinrin meje náà sẹ́yìn; ṣugbọn Mose dìde, ó ran àwọn ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ó sì fún àwọn ẹran wọn ní omi mu.
18 Nígbà tí wọ́n pada dé ọ̀dọ̀ Reueli, baba wọn, ó bi wọ́n pé, “Ó ṣe ya yín tó báyìí lónìí?”
19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ijipti kan ni ó gbà wá kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan náà, ó tilẹ̀ tún bá wa pọn omi fún agbo ẹran wa.”
20 Reueli bá bi àwọn ọmọ rẹ̀ léèrè pé, “Níbo ni ará Ijipti ọ̀hún wà? Kí ló dé tí ẹ fi sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wọlé, kí ó wá jẹun.”
21 Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya.
22 Ó bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọmọ náà ní Geriṣomu, ó wí pé, “Mo jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”
23 Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, ọba Ijipti kú, àwọn ọmọ Israẹli sì ń kérora ní oko ẹrú tí wọ́n wà, wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Igbe tí wọn ń ké ní oko ẹrú sì gòkè tọ OLUWA lọ.
24 Ọlọrun gbọ́ ìkérora wọn, ó sì ranti majẹmu tí ó bá Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu dá.
25 Ọlọrun bojú wo àwọn eniyan Israẹli, ó sì rí irú ipò tí wọ́n wà.