Ẹkisodu 20 BM

Òfin Mẹ́wàá

1 Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní,

2 “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà:

3 “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.

4 “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.

5 O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

6 Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

7 “O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi.

8 “Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́.

9 Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe.

10 Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀.

11 Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́.

12 “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn lórí ilẹ̀ tí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ.

13 “O kò gbọdọ̀ paniyan.

14 “O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga.

15 “O kò gbọdọ̀ jalè.

16 “O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnikeji rẹ.

17 “O kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ọmọnikeji rẹ, tabi sí aya rẹ̀ tabi sí iranṣẹ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, tabi sí akọ mààlúù rẹ̀, tabi sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi sí ohunkohun tí ó jẹ́ ti ọmọnikeji rẹ.”

Ẹ̀rù Ba Àwọn Ọmọ Israẹli

18 Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè,

19 wọ́n sì wí fún Mose pé, “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a óo máa gbọ́; má jẹ́ kí Ọlọrun bá wa sọ̀rọ̀ mọ́, kí a má baà kú.”

20 Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, Ọlọrun wá dán yín wò ni, kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.”

21 Àwọn eniyan náà dúró lókèèrè, bí Mose tí ń súnmọ́ òkùnkùn biribiri tí ó ṣú bo ibi tí Ọlọrun wà.

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Jẹmọ́ Ibi Pẹpẹ

22 OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ ti rí i fúnra yín pé mo ba yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.

23 Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn.

24 Yẹ̀ẹ̀pẹ̀ ni kí ẹ fi tẹ́ pẹpẹ fún mi, kí ẹ sì máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí rẹ̀, kì báà ṣe aguntan tabi mààlúù. Níbikíbi tí mo bá pa láṣẹ pé kí ẹ ti sìn mí, n óo tọ̀ yín wá, n óo sì súre fún yín níbẹ̀.

25 Bí ẹ bá fi òkúta tẹ́ pẹpẹ fún mi, ẹ má lo òkúta tí wọ́n bá gbẹ́, nítorí pé bí ẹ bá fi ohun èlò yín ṣiṣẹ́ lára òkúta náà, ẹ ti sọ ọ́ di aláìmọ́.

26 Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ́ pẹpẹ tí ẹ óo máa fi àtẹ̀gùn gùn, kí wọ́n má baà máa rí ìhòòhò yín lórí rẹ̀.