Ẹkisodu 10 BM

1 OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.

2 Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

3 Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun.

4 Nítorí pé bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, ó ní òun yóo mú kí eṣú wọ ilẹ̀ rẹ lọ́la.

5 Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko.

6 Wọn yóo rọ́ kún gbogbo ààfin rẹ ati ilé gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ ati ilé gbogbo àwọn ará Ijipti, àwọn eṣú náà yóo burú ju ohunkohun tí àwọn baba ati àwọn baba ńlá yín ti rí rí lọ, láti ọjọ́ tí wọ́n ti dáyé títí di òní olónìí.” Mose bá yipada kúrò níwájú Farao.

7 Àwọn ẹmẹ̀wà Farao sọ fún un pé, “Kabiyesi, ìgbà wo ni ọkunrin yìí yóo yọ wá lẹ́nu dà? Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ kí wọ́n lè lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn. Àbí kò tíì hàn sí kabiyesi báyìí pé gbogbo Ijipti tí ń parun tán lọ ni?”

8 Wọ́n bá mú Mose ati Aaroni pada tọ Farao lọ. Farao ní kí wọ́n lọ sin OLUWA Ọlọrun wọn, ṣugbọn ó bèèrè pé àwọn wo gan-an ni yóo lọ?

9 Mose dáhùn pé, “Gbogbo wa ni à ń lọ, ati àgbà ati èwe; ati ọkunrin ati obinrin, ati gbogbo agbo mààlúù wa, ati gbogbo agbo ẹran wa, nítorí pé a níláti lọ ṣe àjọ̀dún kan fún OLUWA.”

10 Farao bá dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín bí mo bá jẹ́ kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín lọ. Wò ó, ète burúkú wà ní ọkàn yín.

11 N ò gbà! Ẹ̀yin ọkunrin nìkan ni kí ẹ lọ sin OLUWA; nítorí pé bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ fẹ́ àbí?” Wọ́n bá lé wọn jáde kúrò níwájú Farao.

12 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Ijipti, kí eṣú lè tú jáde, kí wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n jẹ gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà tí yìnyín kò pa.”

13 Mose bá gbé ọ̀pá rẹ̀, ó nà án sókè, sórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti. OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà fẹ́ sórí gbogbo ilẹ̀ náà, ní gbogbo ọ̀sán ati ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Nígbà tí yóo fi di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, afẹ́fẹ́ ti kó eṣú dé.

14 Eṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, wọ́n sì bà sí gbogbo ilẹ̀. Wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé irú rẹ̀ kò sí rí, irú rẹ̀ kò sì tún tíì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti ìgbà náà.

15 Nítorí pé wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo ojú ọ̀run ṣókùnkùn dudu, wọ́n sì jẹ gbogbo ewé, ati gbogbo èso tí ń bẹ lórí igi, ati koríko tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa. Ẹyọ ewé kan kò kù lórí igi, tabi koríko, tabi ohun ọ̀gbìn kan ninu oko, jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.

16 Farao bá yára pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín ati sí ẹ̀yin pàápàá.

17 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.”

18 Mose bá jáde kúrò níwájú Farao, ó lọ gbadura sí OLUWA.

19 OLUWA bá yí afẹ́fẹ́ líle ìwọ̀ oòrùn pada, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn eṣú náà lọ sí inú Òkun Pupa, ẹyọ eṣú kan ṣoṣo kò sì kù mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

20 Ṣugbọn OLUWA tún mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

21 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, kí òkùnkùn lè ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti, òkùnkùn biribiri tí eniyan fẹ́rẹ̀ lè dì mú.”

22 Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún odidi ọjọ́ mẹta.

23 Wọn kò lè rí ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì dìde kúrò níbi tí ó wà fún ọjọ́ mẹta. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ wà ní gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé.

24 Farao bá tún ranṣẹ lọ pe Mose, ó ní, “Ẹ lọ sin Ọlọrun yín, ẹ máa kó àwọn ọmọ yín lọ pẹlu, ṣugbọn ẹ fi agbo aguntan yín ati agbo ẹran yín sílẹ̀.”

25 Mose dáhùn pé, “O níláti jẹ́ kí á kó ẹran tí a óo fi rúbọ lọ́wọ́, ati èyí tí a óo fi rúbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun wa.

26 A níláti kó àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ, a kò ní fi ohunkohun sílẹ̀ lẹ́yìn, nítorí pé ninu wọn ni a óo ti mú láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa; a kò sì tíì mọ ohun tí a óo fi rúbọ, àfi ìgbà tí a bá débẹ̀.”

27 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ.

28 Farao bá lé Mose, ó ní, “Kúrò lọ́dọ̀ mi; kí o sì ṣọ́ra rẹ gidigidi, n kò gbọdọ̀ tún rí ọ níwájú mi mọ́; ní ọjọ́ tí mo bá tún fi ojú kàn ọ́, ọjọ́ náà ni o óo kú!”

29 Mose bá dáhùn, ó ní, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí. N kò ní dé iwájú rẹ mọ́.”