1 “Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù,
2 mú burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ati àkàrà dídùn tí kò ní ìwúkàrà tí a fi òróró pò, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró sí lórí. Ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí o fi ṣe wọ́n.
3 Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà.
4 “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.
5 Lẹ́yìn náà, kó àwọn aṣọ náà, wọ Aaroni lẹ́wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu, ati efodu náà, ati ìgbàyà. Lẹ́yìn náà, fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dì í ní àmùrè.
6 Fi fìlà náà dé e lórí, kí o sì gbé adé mímọ́ lé orí fìlà náà.
7 Gbé òróró ìyàsọ́tọ̀, kí o dà á lé e lórí láti yà á sọ́tọ̀.
8 “Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá, kí o sì wọ̀ wọ́n lẹ́wù,
9 dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi.
10 “Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí.
11 Lẹ́yìn náà, pa akọ mààlúù náà níwájú OLUWA lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
12 Gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, kí o fi ìka rẹ tọ́ ọ sí ara ìwo pẹpẹ, kí o sì da ìyókù rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.
13 Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà.
14 Ṣugbọn lẹ́yìn ibùdó ni kí o ti fi iná sun ẹran ara rẹ̀, ati awọ rẹ̀, ati nǹkan inú rẹ̀, nítorí pé, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
15 “Lẹ́yìn náà, mú ọ̀kan ninu àwọn àgbò mejeeji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí.
16 Lẹ́yìn náà, pa àgbò náà, sì gba ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o dà á sí ara pẹpẹ yíká.
17 Gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Dà wọ́n mọ́ àwọn tí o gé wẹ́wẹ́ ati orí rẹ̀,
18 kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun.
19 “Lẹ́yìn náà, mú àgbò keji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí.
20 Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká.
21 Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu.
22 “Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni.
23 Mú burẹdi kan, àkàrà dídùn kan pẹlu òróró, ati burẹdi pẹlẹbẹ láti inú agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí ó wà níwájú OLUWA.
24 Kó gbogbo wọn lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLUWA.
25 Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni.
26 “Mú igẹ̀ àgbò tí a fi ya Aaroni sí mímọ́, kí o sì fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, èyí ni yóo jẹ́ ìpín tìrẹ.
27 “O óo ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́ ati itan tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa lára àgbò ìyàsímímọ́, nítorí pé, ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni.
28 Yóo máa jẹ́ ìpín ìran wọn títí lae, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa fún àwọn alufaa lára ẹbọ alaafia wọn; ẹbọ wọn sí OLUWA ni.
29 “Ẹ̀wù mímọ́ Aaroni yóo di ti arọmọdọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn aṣọ mímọ́ náà ni wọn yóo máa wọ̀; wọn yóo máa wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi àmì òróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́.
30 Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ.
31 “Mú àgbò ìyàsímímọ́ náà, kí o sì bọ ẹran ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan.
32 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo sì jẹ ẹran àgbò náà, ati burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
33 Wọn yóo jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, eniyan tí kì í bá ṣe alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni wọ́n.
34 Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni.
35 “Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́.
36 Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́.
37 Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu.
38 “Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan.
39 Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́.
40 Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.
41 Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.
42 Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀.
43 Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́.
44 N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa.
45 N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.
46 Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.