Ẹkisodu 33 BM

OLUWA Pàṣẹ Pé Kí Àwọn Eniyan Israẹli Kúrò ní Òkè Sinai

1 OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.

2 N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde.

3 Ẹ lọ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá náà, tí ó kún fún wàrà ati oyin; n kò ní sí ní ààrin yín nígbà tí ẹ bá ń lọ, nítorí orí kunkun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo pa yín run lójú ọ̀nà.”

4 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá.

5 Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe.

6 Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu.

Àgọ́ Wíwà OLUWA

7 Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.

8 Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

9 Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀.

10 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

11 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ.

OLUWA Ṣèlérí láti Wà Pẹlu Àwọn Eniyan Rẹ̀

12 Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ.

13 Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.”

14 OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.”

15 Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín.

16 Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”

17 OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.”

18 Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.”

19 OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.”

20 OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.”

21 OLUWA tún dáhùn pé, “Ibìkan wà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, wá dúró lórí òkúta kan níbẹ̀.

22 Nígbà tí ògo mi bá ń kọjá lọ, n óo pa ọ́ mọ́ ninu ihò òkúta yìí, n óo sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ lójú nígbà tí mo bá ń rékọjá.

23 Lẹ́yìn náà, n óo ká ọwọ́ mi kúrò, o óo sì rí àkẹ̀yìnsí mi, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí ojú mi.”