Ẹkisodu 15 BM

Orin Mose

1 Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní:“N óo kọrin sí OLUWA,nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo.Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa.

2 OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi,n óo máa yìn ín.Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi;n óo máa gbé e ga.

3 Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀.

4 Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun,ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa.

5 Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta.

6 Agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ pọ̀ jọjọ, OLUWA;OLUWA, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

7 Ninu títóbi ọláńlá rẹ, o dojú àwọn ọ̀tá rẹ bolẹ̀,o fa ibinu yọ, ó sì jó wọn bí àgékù koríko.

8 Èémí ihò imú rẹ mú kí omi gbájọ,ìkún omi dúró lóòró bí òkítì,ibú omi sì dì ní ìsàlẹ̀ òkun.

9 Ọ̀tá wí pé,‘N óo lé wọn, ọwọ́ mi yóo sì tẹ̀ wọ́n;n óo pín ìkógun,n óo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi lọ́rùn lára wọn.N óo fa idà mi yọ,ọwọ́ mi ni n óo sì fi pa wọ́n run.’

10 Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá.

11 “Ta ló dàbí rẹ OLUWA ninu àwọn oriṣa?Ta ló dàbí rẹ, ológo mímọ̀ jùlọ?Ẹlẹ́rù níyìn tíí ṣe ohun ìyanu.

12 O na ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ilẹ̀ sì yanu, ó gbé wọn mì.

13 O ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ṣe amọ̀nà àwọn eniyan rẹ tí o rà pada,o ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ.

14 Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì,jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini.

15 Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu,ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu,gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára.

16 Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati jìnnìjìnnì ti dà bò wọ́n,nítorí títóbi agbára rẹ, OLUWA,wọ́n dúró bí òkúta,títí tí àwọn eniyan rẹ fi kọjá lọ,àní àwọn tí o ti rà pada.

17 O óo kó àwọn eniyan rẹ wọlé,o óo sì fi ìdí wọn múlẹ̀ lórí òkè mímọ́ rẹ,níbi tí ìwọ OLUWA ti pèsè fún ibùgbé rẹ,ibi mímọ́ rẹ tí ìwọ OLUWA ti fi ọwọ́ ara rẹ pèsè sílẹ̀.

18 OLUWA yóo jọba títí lae ati laelae.”

Orin Miriamu

19 Nígbà tí àwọn ẹṣin Farao, ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọ inú òkun, OLUWA mú kí omi òkun pada bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn eniyan Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ láàrin òkun.

20 Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó.

21 Miriamu bá dá orin fún wọn pé,“Ẹ kọrin sí OLUWA,nítorí tí ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo,ó ti da ati ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin sinu Òkun Pupa.”

Omi Kíkorò

22 Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú láti ibi Òkun Pupa, wọ́n ń lọ sí aṣálẹ̀ Ṣuri, ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi rìn ninu aṣálẹ̀ láìrí omi.

23 Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi tí wọ́n rí níbẹ̀, nítorí pé ó korò. Nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ ibẹ̀ ní Mara, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe ìkorò.

24 Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?”

25 Mose bá kígbe sí OLUWA, OLUWA fi igi kan hàn án. Mose ju igi náà sinu omi, omi náà sì di dídùn.Ibẹ̀ ni OLUWA ti fún wọn ní ìlànà ati òfin, ó sì dán wọn wò,

26 ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.”

27 Lẹ́yìn náà ni wọ́n dé Elimu, níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́bàá àwọn orísun omi náà.