19 Bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá wú, tí ó funfun tabi tí ó pọ́n, kí olúwarẹ̀ lọ fihan alufaa.
20 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo.
21 Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.
22 Bí àrùn yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri lára olúwarẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.
23 Ṣugbọn bí àmì yìí kò bá paradà níbi tí ó wà, tí kò sì tàn káàkiri, àpá oówo lásán ni, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́.
24 “Tabi bí iná bá jó eniyan lára, tí ó sì di egbò, tí ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n tabi tí ó funfun,
25 kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun, tí ó sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde níbi tí iná ti jó olúwarẹ̀. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.