2 “Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa.
3 Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́.
4 Ṣugbọn bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, kí alufaa ti abirùn náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.
5 Ní ọjọ́ keje, alufaa náà yóo yẹ abirùn náà wò, bí àrùn náà kò bá tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.
6 Nígbà tí ó bá tún di ọjọ́ keje, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà bá bẹ̀rẹ̀ sí wòdú, tí àrùn náà kò sì tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́, ara rẹ̀ wú lásán ni; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì di mímọ́.
7 Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa.
8 Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.