7 Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa.
8 Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.
9 “Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ.
10 Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò,
11 a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni.
12 Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan,
13 nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́.