Lefitiku 14:6-12 BM

6 Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn.

7 Yóo wọ́n ọn sí ara ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ náà nígbà meje. Lẹ́yìn náà alufaa yóo pè é ní mímọ́, yóo sì jẹ́ kí ẹyẹ keji tí ó wà láàyè, fò wọ igbó lọ.

8 Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.

9 Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́.

10 “Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ.

11 Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

12 Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.