15 “Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí.
16 Bẹ́ẹ̀ ni yóo ti ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, nítorí àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli, ati nítorí ìrékọjá ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì ṣe sí Àgọ́ Àjọ tí ó wà láàrin wọn, nítorí àìmọ́ wọn.
17 Kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu Àgọ́ Àjọ nígbà tí ó bá wọlé lọ láti ṣe ètùtù ninu ibi mímọ́ náà, títí tí yóo fi jáde, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, ati ilé rẹ̀, ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli.
18 Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo.
19 Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli.
20 “Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀.
21 Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀.