Lefitiku 16:18-24 BM

18 Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo.

19 Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli.

20 “Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀.

21 Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀.

22 Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ.

23 “Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.

24 Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà.