29 “Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.
30 Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA.
31 Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae.
32 Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà.
33 Yóo ṣe ètùtù fún Àgọ́ mímọ́ náà, ati Àgọ́ Àjọ, ati pẹpẹ náà, kí ó sì ṣe ètùtù fún àwọn alufaa pẹlu ati ìjọ eniyan náà.
34 Èyí yóo jẹ́ ìlànà ayérayé fun yín, kí wọ́n lè máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.