6 Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀.
7 Lẹ́yìn náà yóo mú àwọn ewúrẹ́ mejeeji, yóo fà wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
8 Lẹ́yìn náà, yóo ṣẹ́ gègé lórí àwọn ewúrẹ́ mejeeji, gègé kan fún OLUWA, ekeji fún Asaseli.
9 Aaroni yóo fa ẹran tí gègé OLUWA bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
10 Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀.
11 “Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.
12 Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà.