7 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ́ ní ọjọ́ kẹta, ohun ìríra ni, kò sì ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́.
8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ẹ́ yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó ti ba ohun mímọ́ OLUWA jẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
9 “Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ, o kò gbọdọ̀ kórè títí kan ààlà. Lẹ́yìn tí o bá ti kórè tán, o kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn ohun tí o bá gbàgbé.
10 O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.
11 “Ẹ kò gbọdọ̀ jalè, ẹ kò gbọdọ̀ fi ìwà ẹ̀tàn bá ara yín lò; ẹ kò sì gbọdọ̀ parọ́ fún ara yín.
12 Ẹ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí ẹ má baà ba orúkọ Ọlọrun yín jẹ́. Èmi ni OLUWA.
13 “Ẹ kò gbọdọ̀ pọ́n aládùúgbò yín lójú tabi kí ẹ jà á lólè; owó iṣẹ́ tí alágbàṣe bá ba yín ṣe kò gbọdọ̀ di ọjọ́ keji lọ́wọ́ yín.