15 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.
16 “Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji;
17 ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni kí ó sun ún.
18 Bí wọ́n bá jẹ ninu ẹran ẹbọ alaafia tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, ẹbọ náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ ẹni tí ó bá rú u, a kò ní kọ ọ́ sílẹ̀ fún un, nítorí pé ohun ìríra ni, ẹni tí ó bá jẹ ẹ́ ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
19 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá kan ohun àìmọ́ kan, sísun ni ẹ gbọdọ̀ sun irú ẹran bẹ́ẹ̀.“Gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ mímọ́ lè jẹ àwọn ẹran yòókù,
20 ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ní àkókò tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.
21 Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”