Nọmba 1 BM

Ètò Ìkànìyàn Àkọ́kọ́ láàrin Àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,

2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

3 Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

4 Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.”

5 Orúkọ àwọn baálẹ̀-baálẹ̀ náà nìwọ̀nyí: Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Reubẹni.

6 Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Simeoni.

7 Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Juda.

8 Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Isakari.

9 Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Sebuluni.

10 Ninu àwọn ọmọ Josẹfu, Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli ọmọ Pedasuri ni yóo sì jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Manase.

11 Abidani ọmọ Gideoni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini.

12 Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Dani.

13 Pagieli ọmọ Okirani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Aṣeri.

14 Eliasafu ọmọ Deueli ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Gadi.

15 Ahira ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Nafutali.

16 Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.

17 Mose ati Aaroni pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní ọjọ́ kinni oṣù keji,

18 pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé.

19 Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

20 Ninu ẹ̀yà Reubẹni, tíí ṣe àkọ́bí Israẹli, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún ọdún sókè, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

21 jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).

22 Ninu ẹ̀yà Simeoni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

23 jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300).

24 Ninu ẹ̀yà Gadi, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

25 jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).

26 Ninu ẹ̀yà Juda, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

27 jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).

28 Ninu ẹ̀yà Isakari, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

29 jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400).

30 Ninu ẹ̀yà Sebuluni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

31 jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400).

32 Ninu ẹ̀yà Efuraimu àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

33 jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).

34 Ninu ẹ̀yà Manase, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

35 jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé igba (32,200).

36 Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

37 jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400).

38 Ninu ẹ̀yà Dani, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

39 jẹ́ ẹgbaa mọkanlelọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (62,700).

40 Ninu ẹ̀yà Aṣeri, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

41 jẹ́ ọ̀kẹ́ meji le ẹẹdẹgbẹjọ (41,500).

42 Ninu ẹ̀yà Nafutali àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

43 jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).

44 Àwọn ni àwọn tí Mose ati Aaroni kà pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí mejila tí a yàn láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

45 Àròpọ̀ iye àwọn ọmọ Israẹli, ní ìdílé-ìdílé, láti ẹni ogún ọdún sókè, àwọn tí wọ́n lè lọ sójú ogun,

46 jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550).

47 Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn,

48 nítorí pé OLUWA ti sọ fún Mose pé,

49 kí ó má ka ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí ó bá ń kà wọ́n.

50 Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.

51 OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.

52 Kí àwọn ọmọ Israẹli yòókù pa àgọ́ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, olukuluku ní ibùdó rẹ̀, lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀.

53 Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”

54 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36