Nọmba 26 BM

Ètò Ìkànìyàn Keji

1 Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé,

2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.”

3 Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,

4 wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

5 Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,

6 ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi.

7 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730).

8 Palu bí Eliabu,

9 Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.

10 Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.

11 Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú.

12 Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini;

13 ìdílé Sera ati ti Ṣaulu.

14 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200).

15 Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni;

16 ìdílé Osini, ati ìdílé Eri;

17 ìdílé Arodu ati ìdílé Areli.

18 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).

19 Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20 Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera.

21 Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli.

22 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500).

23 Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua;

24 ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi.

25 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300).

26 Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli.

27 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500).

28 Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu.

29 Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi.

30 Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki;

31 ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu;

32 ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi.

33 Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa.

34 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ìdílé Manase jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (52,700).

35 Àwọn ọmọ Efuraimu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣutela, ìdílé Bekeri ati ìdílé Tahani.

36 Àwọn ọmọ Ṣutela nìwọ̀nyí, ìdílé Erani.

37 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Efuraimu jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (32,500). Àwọn ni ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé.

38 Àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Bela, ìdílé Aṣibeli, ìdílé Ahiramu;

39 ìdílé Ṣefufamu ati ìdílé Hufamu.

40 Àwọn ọmọ Bela nìwọ̀nyí: ìdílé Aridi ati ìdílé Naamani.

41 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé ẹgbẹjọ (45,600).

42 Àwọn ọmọ Dani ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣuhamu.

43 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400).

44 Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria.

45 Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli.

46 Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera.

47 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).

48 Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni,

49 ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu.

50 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400).

51 Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).

52 OLUWA sọ fún Mose pé,

53 “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

54 Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.

55 Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

56 Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.”

57 Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari,

58 Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu.

59 Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.

60 Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

61 Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́.

62 Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.

63 Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí.

64 Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai.

65 Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36