1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:
2 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.
3 Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn.
4 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).
5 Kí ẹ̀yà Isakari pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Juda; Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí wọn.
6 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400).
7 Kí ẹ̀yà Sebuluni pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Isakari. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí wọn.
8 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400).
9 Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Juda jẹ́ ẹgbaa mẹtalelaadọrun-un ó lé irinwo (186,400). Àwọn ni yóo máa ṣáájú nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.
10 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn.
11 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).
12 Ẹ̀yà Simeoni ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Reubẹni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí wọn.
13 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300).
14 Ẹ̀yà Gadi ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Simeoni; Eliasafu ọmọ Reueli ni yóo jẹ́ olórí wọn.
15 Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).
16 Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Reubẹni jẹ́ ẹgbaa marundinlọgọrin ó lé aadọta lé ní egbeje (151,450). Àwọn ni yóo máa tẹ̀lé ibùdó Juda nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.
17 Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.
18 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.
19 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).
20 Ẹ̀yà Manase ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli, ọmọ Pedasuri, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.
21 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaafa ó lé igba (32,200).
22 Ẹ̀yà Bẹnjamini ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Manase; Abidoni, ọmọ Gideoni ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.
23 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400).
24 Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọ̀kẹ́ marun-un ó lé ẹgbaarin ati ọgọrun-un (108,100). Àwọn ni wọn yóo jẹ́ ìpín kẹta tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣí láti ibùdó kan sí òmíràn.
25 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Dani yóo wà ní ìhà àríwá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Ahieseri, ọmọ Amiṣadai, ni yóo jẹ́ olórí wọn.
26 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹsan-an (62,700).
27 Ẹ̀yà Aṣeri ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Dani; Pagieli, ọmọ Okirani, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.
28 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (41,500).
29 Lẹ́yìn náà ni ẹ̀yà Nafutali; Ahira, ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí wọn.
30 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbaaje ati irinwo (53,400).
31 Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, jẹ́ ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹẹdẹgbaasan-an ati ẹgbẹta (157,600). Àwọn ni wọn yóo tò sẹ́yìn patapata.
32 Ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí a kà, gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àgọ́ tí a kà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹtadinlogun ati aadọjọ (603,550).
33 Ṣugbọn a kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.
34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n pàgọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú, olukuluku wà ninu ìdílé tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.