Nọmba 4 BM

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi–Ìdílé Kohati

1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:

2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrin àwọn ọmọ Lefi, ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

3 Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

4 Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ ninu Àgọ́ Àjọ.

5 “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà.

6 Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.

7 “Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.

8 Lẹ́yìn náà, wọn yóo da aṣọ pupa ati awọ dídán bò ó. Wọn yóo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.

9 “Wọn yóo fi aṣọ aláwọ̀ aró bo ọ̀pá fìtílà ati àwọn fìtílà rẹ̀ ati àwọn ohun tí à ń lò pẹlu rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò òróró.

10 Wọn yóo sì fi awọ dídán dì wọ́n, wọn yóo sì gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.

11 “Lẹ́yìn èyí, wọn óo da aṣọ aláwọ̀ aró bo pẹpẹ wúrà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò ó, wọn óo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.

12 Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.

13 Wọn óo kó eérú kúrò lórí pẹpẹ, wọn óo fi aṣọ elése àlùkò bò ó.

14 Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.

15 Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú.

16 “Eleasari ọmọ Aaroni Alufaa ni yóo ṣe ìtọ́jú òróró fìtílà, ati turari olóòórùn dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró ìyàsímímọ́, ati gbogbo Àgọ́ náà. Yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati àwọn ohun èlò ibẹ̀.”

17 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,

18 “Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi,

19 ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé.

20 Àwọn ìdílé Kohati kò gbọdọ̀ wọ inú ibi mímọ́ láti yọjú wo àwọn ohun mímọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá yọjú wò wọ́n yóo kú.”

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi–Ìdílé Geriṣoni

21 OLUWA sọ fún Mose pé,

22 “Ka iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn:

23 ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

24 Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí:

25 Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

26 Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi.

27 Kí Mose yan àwọn ọmọ Geriṣoni sí ìtọ́jú àwọn ẹrù, kí ó sì rí i pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa láṣẹ fún wọn nípa iṣẹ́ wọn.

28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Geriṣoni ninu Àgọ́ Àjọ nìyí, Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi–Ìdílé Merari

29 OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

30 Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

31 Àwọn ọmọ Merari ni yóo máa ru àwọn igi férémù Àgọ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

32 Àwọn òpó àyíká àgbàlá ati ìtẹ́lẹ̀ wọn, àwọn èèkàn àgọ́, okùn wọn, ati gbogbo ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Olukuluku yóo sì mọ ẹrù tirẹ̀.

33 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Merari ninu Àgọ́ Àjọ nìyí. Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”

Iye Àwọn Ọmọ Lefi

34 Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli ka àwọn ọmọ Kohati ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

35 Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé ẹni aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

36 Iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹrinla ó dín aadọta (2,750).

37 Iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Kohati nìyí, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

38 Iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

39 láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ

40 jẹ́ ẹgbẹtala ó lé ọgbọ̀n (2,630).

41 Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Geriṣoni tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

42 Àwọn tí a kà ninu àwọn ọmọ Merari, ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

43 láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ

44 jẹ́ ẹgbẹrindinlogun (3,200).

45 Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Merari gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.

46 Gbogbo àwọn tí Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli kà ninu àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn,

47 láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, gbogbo àwọn tí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ati iṣẹ́ ẹrù rírù ninu Àgọ́ Àjọ

48 jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta ó dín ogún (8,580).

49 Mose ka àwọn eniyan náà, ó sì yan iṣẹ́ fún olukuluku wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36