Nọmba 23 BM

Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ

1 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”

2 Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3 Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.

4 Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”

5 OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un.

6 Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.

7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,kí o sì fi Israẹli ré.’

8 Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?

9 Mo rí wọn láti òkè gíga,mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”

11 Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”

12 Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ

13 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

14 Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”

16 OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.

17 Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.

18 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Balaki, dìde, wá gbọ́,fetí sí mi, ọmọ Sipori;

19 Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.

20 OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn,Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.

21 Kò rí ìparun ninu Jakọbu,bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli.OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn,Òun sì ni ọba wọn.

22 OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá,Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré.

23 Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu,bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli.Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé,‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’

24 Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun,ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun.Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán,tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.”

25 Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.”

26 Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?”

Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ

27 Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.”

28 Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.

29 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.”

30 Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36