Nọmba 7 BM

Ẹbọ Àwọn Olórí

1 Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀,

2 àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli,

3 mú ọrẹ ẹbọ wá siwaju OLUWA. Ọkọ̀ ẹrù mẹfa ati akọ mààlúù mejila. Ọkọ̀ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún olórí meji meji, ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan fún olórí kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mú àwọn ẹbọ wọnyi wá sí ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́.

4 OLUWA sọ fún Mose pé

5 kí ó gba àwọn ẹbọ náà lọ́wọ́ wọn fún lílò ninu Àgọ́ Àjọ, kí ó sì pín wọn fún olukuluku àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn olukuluku wọn ti rí.

6 Mose bá gba àwọn ọkọ̀ ẹrù ati àwọn akọ mààlúù náà, ó kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi.

7 Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn.

8 Ó fún àwọn ọmọ Merari ní ọkọ̀ ẹrù mẹrin ati akọ mààlúù mẹjọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn, lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni alufaa.

9 Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́.

10 Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ.

11 OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.”

12 Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá.

13 Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

14 Àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;

15 akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

16 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

17 Ó kó àwọn nǹkan wọnyi kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia: akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu.

18 Ní ọjọ́ keji ni Netaneli ọmọ Suari olórí ẹ̀yà Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

19 Ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ;

20 ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;

21 akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

22 òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

23 Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Wọ́n jẹ́ ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.

24 Ní ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olórí ẹ̀yà Sebuluni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

25 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní Àgọ́ Àjọ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

26 Ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari.

27 Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun.

28 Òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

29 Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.

30 Ní ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olórí ẹ̀yà Reubẹni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

31 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ,

32 ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari.

33 Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

34 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

35 Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ alaafia. Ọrẹ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri nìyí.

36 Ní ọjọ́ karun-un, Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai, olórí ẹ̀yà Simeoni mú ọrẹ tirẹ̀ wa.

37 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

38 Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari,

39 akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

40 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

41 Lẹ́yìn náà, Ṣelumieli, ọmọ Suriṣadai tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

42 Ní ọjọ́ kẹfa ni Eliasafu, ọmọ Deueli, olórí àwọn ẹ̀yà Gadi, mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

43 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin (70) ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

44 Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari,

45 akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

46 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

47 Lẹ́yìn náà Eliasafu, ọmọ Deueli, tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

48 Ní ọjọ́ keje ni Eliṣama ọmọ Amihudu, olórí àwọn ẹ̀yà Efuraimu mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

49 Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli ati abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

50 Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.

51 Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

52 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

53 Eliṣama, ọmọ Amihudu, kó akọ mààlúù meji, ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

54 Ní ọjọ́ kẹjọ ni Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ẹ̀yà Manase mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ wá.

55 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

56 Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari,

57 akọ mààlúù kékeré kan, ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

58 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

59 Gamalieli ọmọ Pedasuri, kó àwọn akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

60 Ní ọjọ́ kẹsan-an ni Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

61 Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọ́n ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.

62 Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.

63 Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

64 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

65 Abidani ọmọ Gideoni, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.

66 Ní ọjọ́ kẹwaa ni Ahieseri ọmọ Amiṣadai, olórí àwọn ẹ̀yà Dani mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

67 Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.

68 Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.

69 Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

70 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

71 Ahieseri ọmọ Amiṣadai, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.

72 Ní ọjọ́ kọkanla ni Pagieli ọmọ Okirani, olórí àwọn ẹ̀yà Aṣeri mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

73 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.

74 Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari;

75 akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,

76 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

77 Pagieli ọmọ Okirani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un kalẹ̀, pẹlu òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, fún ẹbọ alaafia.

78 Ní ọjọ́ kejila ni Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn ẹ̀yà Nafutali, mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

79 Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, pẹlu abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.

80 Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;

81 akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

82 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

83 Ahira, ọmọ Enani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.

84 Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila,

85 ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n.

86 Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli.

87 Gbogbo mààlúù tí wọ́n mú wá fún ọrẹ ẹbọ sísun jẹ́ mejila ati àgbò mejila, ọ̀dọ́ àgbò mejila ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Wọ́n tún mú òbúkọ mejila wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

88 Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i.

89 Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, ó gbọ́ ohùn kan tí ń bá a sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, láàrin àwọn kerubu mejeeji. Ẹni náà bá Mose sọ̀rọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36