Nọmba 24 BM

1 Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,

2 ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,

3 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú;

4 ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀.

5 Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu,ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli!

6 Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ,bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò.Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn,ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

7 Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀,omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀;àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu.Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ,ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

8 Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá,ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré.Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run,wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

9 Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun,bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde?Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli,ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!”

10 Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!

11 Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.”

12 Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé,

13 bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkẹyìn tí Balaamu Sọ

14 Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”

15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.

16 Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun,tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ,tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì.

17 Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ,mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ.Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu,ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá;yóo run àwọn àgbààgbà Moabu,yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.

18 Yóo ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Edomu,yóo sì gba ilẹ̀ wọn.Yóo ṣẹgun àwọn ará Seiri tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn,yóo sì gba ilẹ̀ wọn.Israẹli yóo sì máa pọ̀ sí i ní agbára.

19 Láti inú ìdílé Jakọbu ni àṣẹ ọba yóo ti jáde wá,yóo sì pa àwọn tí ó kù ninu ìlú náà run.”

20 Nígbà tí ó wo Amaleki, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:“Amaleki ni orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jùlọ,Ṣugbọn yóo ṣègbé níkẹyìn.”

21 Nígbà tí ó wo àwọn ará Keni, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:“Ibi ìpamọ́ tí ẹ̀ ń gbédàbí ìtẹ́ tí ó wà lórí àpáta gíga.

22 Ṣugbọn ẹ̀yin ará Keni yóo di ẹni ìparun,àwọn ará Aṣuri yóo ko yín lẹ́rú.”

23 Balaamu tún fi òwe sọ ọ̀rọ̀ wọnyi:“Ta ni yóo là nígbà tí Ọlọrun bá ṣe nǹkan wọnyi?

24 Àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n kún fún ọmọ ogun yóo wá láti Kitimu,wọn yóo borí àwọn ará Aṣuri ati Eberi,ṣugbọn Kitimu pàápàá yóo ṣègbé.”

25 Balaamu bá dìde, ó pada sí ilé rẹ̀; Balaki náà bá pada sí ilé rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36