Nọmba 29 BM

Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun

1 “Ní ọjọ́ kinni oṣù keje, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ẹ óo máa fun fèrè.

2 Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.

3 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa kan fún àgbò;

4 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan,

5 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

6 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù

7 “Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

8 Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

9 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan;

10 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan,

11 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.”

Ẹbọ Àjọ̀dún Àgọ́

12 “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò ní ṣe iṣẹ́ kankan fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún náà. Àjọ̀dún àyẹ́sí ni fún OLUWA.

13 Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹtala, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

14 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa, fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kọ̀ọ̀kan,

15 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

16 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

17 “Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

18 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni,

19 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

20 “Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

21 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;

22 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

23 “Ní ọjọ́ kẹrin, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹ́wàá, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

24 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;

25 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

26 “Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

27 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,

28 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

29 “Ní ọjọ́ kẹfa, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹjọ, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

30 Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni;

31 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

32 “Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

33 Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,

34 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

35 “Ní ọjọ́ kẹjọ ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì ní gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

36 Ẹ máa fi akọ mààlúù kan ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLÚWA.

37 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ọjọ́ kinni;

38 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

39 “Àwọn ni àwọn ẹbọ tí ẹ óo máa rú sí OLUWA ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín, pẹlu ẹ̀jẹ́ yín, ẹbọ ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹbọ sísun yín, ẹbọ ohun jíjẹ yín, ati ẹbọ ohun mímu yín, ati ẹbọ alaafia yín.”

40 Mose sọ gbogbo rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36