Nọmba 5 BM

Àwọn Aláìmọ́

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú.

3 Ẹ kó wọn sí ẹ̀yìn odi kí wọn má baà sọ ibùdó yín di aláìmọ́ nítorí pé mò ń gbé inú rẹ̀ pẹlu àwọn eniyan mi.”

4 Àwọn ọmọ Israẹli sì yọ wọ́n kúrò láàrin wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.

Ìjìyà fún Ẹ̀ṣẹ̀

5 OLUWA sọ fún Mose pé:

6 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnikẹ́ni, bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó bá rú òfin Ọlọ́run, tí olúwarẹ̀ sì jẹ̀bi, kí báà ṣe ọkunrin tabi obinrin,

7 olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀.

8 Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

9 Àwọn alufaa ni wọ́n ni gbogbo àwọn ohun ìrúbọ, ati gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá sọ́dọ̀ wọn.

10 Olukuluku alufaa yóo kó ohun tí wọ́n bá mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀.”

Àwọn Aya Tí Ọkọ Wọn Bá Fura sí

11 OLUWA sọ fún Mose pé

12 kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí aya ẹnìkan bá ṣìṣe, tí ó hu ìwà àìtọ́ sí i;

13 tí ọkunrin mìíràn bá bá a lòpọ̀, ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ kò ká wọn mọ́; ṣugbọn tí ó di ẹni ìbàjẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹlẹ́rìí nítorí pé ẹnìkankan kò rí wọn;

14 tabi bí ẹnìkan bá ń jowú tí ó sì rò pé ọkunrin kan ń bá iyawo òun lòpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀,

15 kí olúwarẹ̀ mú iyawo rẹ̀ wá sọ́dọ̀ alufaa, kí ó sì mú ọrẹ rẹ̀ tíí ṣe ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun ọkà baali wá fún alufaa. Kò gbọdọ̀ da òróró sí orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ fi turari sinu rẹ̀, nítorí pé ẹbọ owú ni, tí a rú láti múni ranti àìdára tí eniyan ṣe.

16 “Alufaa yóo sì mú kí obinrin náà dúró níwájú pẹpẹ OLUWA,

17 yóo da omi mímọ́ sinu àwo kan, yóo bù lára erùpẹ̀ ilẹ̀ Àgọ́ Àjọ sinu omi náà.

18 Lẹ́yìn náà, alufaa yóo mú obinrin náà wá siwaju OLUWA, yóo tú irun orí obinrin náà, yóo sì gbé ẹbọ ìrántí lé e lọ́wọ́, tíí ṣe ẹbọ ohun jíjẹ ti owú. Àwo omi kíkorò, tí ó ń mú ègún wá yóo sì wà lọ́wọ́ alufaa.

19 Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi.

20 Ṣugbọn bí o bá tí ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ (níwọ̀n ìgbà tí o wà ní ilé rẹ̀), tí o sì ti sọ ara rẹ di aláìmọ́ nípa pé ọkunrin mìíràn bá ọ lòpọ̀,

21 kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú.

22 Kí omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí wọ inú rẹ, kí ó mú kí inú rẹ wú, kí ó sì mú kí abẹ́ rẹ rà.’“Obinrin náà yóo sì dáhùn pé, ‘Amin, Amin.’

23 “Lẹ́yìn èyí, kí alufaa kọ ègún yìí sinu ìwé, kí ó sì fọ̀ ọ́ sinu abọ́ omi kíkorò náà.

24 Kí obinrin náà mu ún, omi náà yóo sì mú kí ó ní ìrora.

25 Nígbà náà ni alufaa yóo gba ẹbọ ohun jíjẹ ti owú náà lọ́wọ́ obinrin náà yóo sì fì í níwájú OLUWA, lẹ́yìn èyí, yóo gbé e sórí pẹpẹ.

26 Lẹ́yìn náà, alufaa yóo bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà fún ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ; lẹ́yìn náà, yóo ní kí obinrin náà mu omi yìí.

27 Bí ó bá jẹ́ pé obinrin náà ti ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ọkunrin mìíràn bá ti bá a lòpọ̀, omi náà yóo korò ninu rẹ̀, yóo sì mú kí inú rẹ̀ wú, kí abẹ́ rẹ̀ sì rà. Yóo sì fi bẹ́ẹ̀ di ẹni ègún láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

28 Ṣugbọn bí obinrin náà kò bá tí ì ba ara rẹ̀ jẹ́, ègún náà kò ní lágbára lórí rẹ̀, yóo sì lóyún.

29 “Èyí ni ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe nígbà tí obinrin bá ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ọkunrin mìíràn bá a lòpọ̀;

30 tabi nígbà tí ọkunrin kan bá ń ṣiyèméjì nípa ìdúró iyawo rẹ̀, ọkunrin náà yóo mú iyawo rẹ̀ wá siwaju OLÚWA, alufaa yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ yìí.

31 Nígbà náà ni ọkunrin náà yóo bọ́ ninu ẹ̀bi, ṣugbọn obinrin náà yóo forí ru ẹ̀bi àìdára tí ó ṣe.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36