1 Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,
2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
3 Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.
4 Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.”