1 Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú.
2 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata.
3 OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.
4 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà,
5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”