19 Láti Matana, wọ́n ṣí lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli wọ́n ṣí lọ sí Bamotu,
20 láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.
21 Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé,
22 “Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”
23 Sihoni kò gbà kí àwọn ọmọ Israẹli gba orí ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Ṣugbọn ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Jahasi ninu aṣálẹ̀.
24 Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára.
25 Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn.