14 Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
15 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”
16 OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.
17 Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.
18 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:“Balaki, dìde, wá gbọ́,fetí sí mi, ọmọ Sipori;
19 Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.
20 OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn,Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.