10 Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!
11 Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.”
12 Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé,
13 bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.”
14 Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”
15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé,“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.
16 Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun,tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ,tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì.