1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:
2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrin àwọn ọmọ Lefi, ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
3 Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
4 Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ ninu Àgọ́ Àjọ.
5 “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà.