27 Kí Mose yan àwọn ọmọ Geriṣoni sí ìtọ́jú àwọn ẹrù, kí ó sì rí i pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa láṣẹ fún wọn nípa iṣẹ́ wọn.
28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Geriṣoni ninu Àgọ́ Àjọ nìyí, Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”
29 OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
30 Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
31 Àwọn ọmọ Merari ni yóo máa ru àwọn igi férémù Àgọ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
32 Àwọn òpó àyíká àgbàlá ati ìtẹ́lẹ̀ wọn, àwọn èèkàn àgọ́, okùn wọn, ati gbogbo ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Olukuluku yóo sì mọ ẹrù tirẹ̀.
33 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Merari ninu Àgọ́ Àjọ nìyí. Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”